'Tsunami' Indonesia gbẹ̀mí ènìyàn tó lé ní 220

Oríṣun àwòrán, Oystein Lund Andersen
Ó ju ènìyàn okòólénígba (220) tó kú nígbà tí òkun ru bo àwọn ìlú bèbè òkún Indonesia lójijì ní alẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta.
Ọ̀kẹ́ àìmoye ni àwọn ilé tí òkun náà TI wọ́ lọ.
Àwọn onímọ̀ ṣàlàyé wí pé Tilẹ̀ tó wà lábẹ́ òkun bá rì ló máa n ṣokunfa òkun ríru náà. Wọ́n tún sọ síwájú pé ọ̀gbún iná inu àpáta tí wọ́n ń pè ní 'Volcano' ní èdè Gẹ̀ẹ́sì ló fa ilẹ̀ rírì abẹ́ omi ọhun.

Oríṣun àwòrán, Social media
Àwọn àwòrán fi hàn bí òkun náà ṣe ya bo ibi igbáfẹ́ bèbè òkun kan tí ó sì wọ́ àwọn to ń fi orin dá àwọn ènìyàn lárayá.

Oríṣun àwòrán, EPA
Àwọn alákóso àjọ tó ń kojú ìṣẹ̀lẹ̀ pájáwìrì ni iye àwọn ti àwọn mọ̀ tó ti kú rèé:
- Agbègbè Pandeglang - 164
- Agbègbè Serang - 11
- Agbègbè Gúúsù Lampung - 48
- AgbègbèTanggamus - 1
Báwo ní ilẹ̀ rírì ṣe ń fa òkun ríru?
Onímọ̀ nípa ọ̀gbun iná inú àpáta (volcano), Jess Phoenix sọ fun BBC pé ti iná inu àpáta bá ti ru jáde nínú ilẹ̀, yoo fọ́ àwọn àpáta sókè, ó sì lè fa ilẹ̀ rírí lábẹ́ òkun, èyí tí yóò wá ya òkun bo ìlú.

Bí iná inu àpáta naá ṣe ru jáde nínú ilẹ̀ rèé.

Oríṣun àwòrán, Oystein Lund Andersen
Tí ẹ bá rántí, oṣù kẹsàn-án, ọdun 2018 ni ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ riri pa ènìyàn to lé ní ẹgbẹ̀rún mejì ní orílẹ̀-èdè náà.
Ni eyi ti inu agbaye bajẹ si ki eleyii to tun ṣẹlẹ lasiko yii.

Oríṣun àwòrán, Gallo Images/Orbital Horizon/Copernicus Sentin














