You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Bíṣọ̀ọ̀bù tọ́wọ́ rẹ̀ kò dilẹ̀ níbi ìsìnkú Aretha Franklin tọrọ àforíjì
Bisọọbu to dari eto nibi isinku gbajugbaja olorin Aretha Franklin lorileede Amẹrika ti tọrọ aforiji fun pe o fọwọ ko akorin kan, Ariana Grande lọmu.
Eyi waye lẹyin ti aworan to se afihan bi Bisọọbu Charles H Ellis III ti se fọwọ ko Ariana Grande mọra to si n tẹ lọmu gbode .
O sọ fun ile isẹ iroyin Assocaited Press pe ''Mi o lerongba lati maa tẹ obinrin kankan lọmu''
"O seese ki n kọja aaye mi tabi ki n maa ba a ṣere ti ko yẹ"
O fi kun ọrọ rẹ pe : "Mo tunbọ tọrọ aforiji."
Oniwaasu naa ni gbogbo awọn osere to wa nibi eto isinku naa yala wọn jẹ ọkunrin tabi obirin loun dimọ .
Sugbọn awọn to wa nibi isinku naa bẹrẹ si ni fi aworan bi Ariana ti se bẹrẹ si ni kọ orin Aretha Franklin ti akọle re n jẹ ''You Make Me Feel Like A Natural Woman.''
Ọpọ eeyan lo lero wi pe ọwọ Bisọọbu naa sun so ke bo ti se n ba ọmọ ọdun meedọgbọn naa sọrọ.
Aforijin to tọrọ waye lẹyin igba ti awọn kan sọ lori ẹrọ ayelujara pe asọ ti Ariana wọ wa sibi isinku naa ko boju mu.
Awọn kan ni bi wọn ti se fi ẹtẹ silẹ ti wọn n pa lapalapa yi jẹ iwa to buru.
Ti wọn si ni iwa ti Bisọọbu naa wu lo yẹ ki wọn gbaju mọ.