You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Fásitì Zambia: Asọ ìwọ̀kuwọ̀ ń kóbá àwọn akẹ́kọ̀ọ́-kùnrin
Gbajugbaja yunifásítì kan lorílèèdè Zambia tí rọ awọn akẹkọ-bìnrin láti yé máa wọ aṣọ to fara síle nítorí pé kó jẹ kí awọn akẹkọ ọkunrin kọjú mọ́ ìwé.
''University of Zambia'' to wa ni olú ìlú orílẹ̀èdè náà, Lusaka, lẹ ìwé ìkìlọ káàkiri ilé ìkàwé pe, kí àwọn akẹkọ-bìnrin múra ni imúra ọmọluabi.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Awọn akẹkọ obìrin tí wa gbarata lórí ìkìlọ yii.
Fálànà gbọ tiè
Dizina Muzeya sọ fún BBC Yorùbá pe "Se bi iwe lo fẹ wa ka, ki lo sun ọ dé idi a n yọjú wo ẹsẹ akẹkọ obìrin?"
"Òun tó ba wà ní kò kojú mọ"
Ṣugbọn èro akẹkọ ọkùnrin kàn, Killion Phiri, ṣe ọtọọtọ lori ikilọ yii, to si ni òun gbé lẹyìn ìgbésẹ náà.
"Ẹ mo wí pé ará àwọn obìnrin máa n fanimọra. Báwo la ṣe fẹ kojú mọ ìwé nígbà tí ẹni tó wọ aṣọ to fara silẹ ba kojú síwá?"
Sùgbọ́n Orílèèdè Zambia bọwọ fún àṣà ati iṣẹṣe púpọ̀.