Titilayo Atiku: Ọkọ́ mi fẹ́ sẹ̀san rere fún Nàíjíríà, ló ṣe ń dìje ipò ààrẹ fún ìgbà kẹta

Àkọlé fídíò, Tititlayo Atiku: Ọkọ́ mi fẹ́ sẹ̀san rere fún Nàíjíríà, ló ṣe ń dìje ipò ààrẹ fún ìgbà kẹta

Aya igbakeji aarẹ tẹlẹ, Hajia Amina Titilayo Abubakar ti kede pe yoo dara ki gbogbo ọmọ Yoruba dide lati gbaruku ti ọkọ rẹ, Atiku Abubakar, to n dije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oselu PDP.

Aya Atiku, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ salaye pe ohun iwuri ni yoo jẹ fun iran Yoruba, ti wọn ba fi ibo gbe ọkọ oun wọle sipo aarẹ, ti oun si di obinrin akọkọ ni Naijiria.

Titilayo Abubakar ni "Ọmọ Yoruba kankan ko tii jẹ obinrin akọkọ ri nilẹ Naijiria, amọ bi ọkọ mi ba di aarẹ, emi ni yoo jẹ obinrin akọkọ lati ilẹ Yoruba ti yoo di obinrin akọkọ ni Naijiria."

Nigba to n salaye idi ti ọkọ rẹ se fẹ tun gbegba ibo aarẹ fun igba kẹta, Titilayo Abubakar ni Atiku Abubakar n wa ọna lati sẹsan rere pada fun orilẹede yii to se e loore ni.

Bakan naa ni aya Atiku Abubakar mẹnuba koko ohun marun ti oludije aarẹ fẹgbẹ oselu PDP naa yoo se to ba dori aleefa lati mu Naijiria goke agba.

"Bi Atiku Abubakar ba ti di aarẹ Naijiria, yoo se ohun marun fun idagbasoke orilẹede yii Naijiria, lara rẹ ni pe yoo mu irẹpọ alailẹgbẹ pada si orilẹede yii.

Iyapa ẹsin ati ẹya ti gba ilẹ yii kan, amọ Atiku yoo mu ki irẹpọ pada wa gẹgẹ bo se rini aadọta ọdun sẹyin, eyi to mu ki awọn obi mi fi lọwọ si pe ki n fẹ Atiku.

Bakan naa ni Atiku yoo da eto aabo to peye pada si Naijiria, ti ọpọ idarudapọ to n waye nipa agbebọn atawọn ajinigbe yoo si di ohun itan."

Aya Atiku Abubakar tun ni bi ọkọ oun ba di aarẹ, alaafia yoo jọba pada ni ẹka eto ẹkọ, ti iyansẹlodi ẹgbẹ olukọ fasiti yoo si di afisẹyin, ti eegun n fi asọ.