You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
PDP primaries list: Mọ̀ síi nípa àwọn tó máa díje dupò gómìnà lábẹ́ àsíà ẹgbẹ́ PDP lẹ́yìn tí wọ́n ti yegé nínú ìdìbò abẹ́lé
Àwọn tó díje dupò gómìnà tó borí nínú ìdìbò abẹ́lé PDP rè éSeyi Makinde ni PDP gbade fún láti díje dupò gómìnà Oyo lẹ́ẹ̀kán síi nínú ìdìbò abẹnu yìí
Orukọ awọn to laluyọ lati dije du ipo gomina ninu idibo gbogboogbo ni Naijiria labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ti jade lẹyin idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu naa.Ìdí tí mo fi fi ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀ - Peter Obi
Kaakiri orilẹede Naijiria ni idibo naa ti waye ni Ọjọ Karundinlọgbọn, Oṣu Karun un, ọdun 2022.
- Ìwé orúkọ àwọn olùdíje tó bórí ìbó abẹ́nú gómìnà ní APC
- Mọ̀ síi nípa àwọn tó máa díje dupò gómìnà lábẹ́ àsíà ẹgbẹ́ PDP lẹ́yìn tí wọ́n ti yegé nínú ìdìbò abẹ́lé
- Àwa mẹ́ta la gbé òkú Timothy Adegoke lọ sí Ede road- Ẹlẹ́rìí Oyetunde Kazeem
- Ọmọ ọdún 19 tí wọ́n sọ sí ẹ̀wọ̀n nitorí ọ̀kadà tó sọnù ti kú
- Gbajúmọ̀ Olórin Banky W ti rí tíkẹ̀ẹ̀tì ẹgbẹ́ òṣèlú PDP gbà láti díje dupò aṣòfin
- Ìjọba kéde òfin kónílé-ó-gbélé ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́sàn-án ní ìpínlẹ̀ Anambra
- Mà á dá fijilanté sílẹ̀, òmìnira á wà fún ìjọba ìbílẹ̀ láti ná owó wọn- Oluwole Oluyede
- Ohun ìbànújẹ́ ló ṣẹlẹ̀ ní Anambra, ẹ dákún mi ò fẹ́ kẹ́nikẹ́ni fi oró ya oró lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà- Buhari
- Àwọn ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí mọ́kànlá pàdánù ẹ̀mi wọn lẹ́yìn iná tó ṣẹ́yọ
- Oriyomi Hamzat wọ gbaga ọlọ́pàá nítorí ọ̀rọ̀ Timothy Adegoke tó kú sílé ìtura Rahman Adedoyin
- Wo ojú àwọn tó fẹ́ díje dupò gómìnà lábẹ́ ẹgbẹ́ APC ní ìpínlẹ̀ Oyo lónìí
Awọn idibo abẹle to lamilaaka ni ti ipinlẹ Delta ati ti Rivers.
Lara awon ipinle miran ti idibo abele ti waye ni ipinle Oyo, Benue, Adamawa, Delta, Kaduna, Taraba, Bauchi, Abia, Akwa Ibom ati bẹẹ bẹ̣e lọ.
Ajọ eleto idibo ni Naijiria, INEC lo ṣakoso eto idibo naa ti awọn ẹṣọ alaabo naa si peju sibẹ wamuwamu.
Ọjọ kẹta , Oṣu Kẹfa ni gbedeke ti Ajọ to n risi eto idibo ni NaIjiria, INEC fun awọn ẹgbẹ oṣelu lati ṣe idibo abẹle wọn.
Adamawa:
Gomina Umaru Fintiri to n dije dupo fun saa keji lo bori ninu eto idibo naa.
Ibo 663 ninu 668 lo fi jawe olubori
Oyo
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde to n dije dupo gomina fun saa keji lo bori ninu idibo abẹle naa
Ibo 1,040 ninu 668 lo fi bori Hazeem Gbolarunmi ti wọn jọ figagbaga.
Benue
Abẹnugan Ile Igbimọ Aṣofin, Titus Uba lo bori ninu eto idibo naa.
Ibo 731 lo fi ṣajulọ fun igbakeji gomina Benue, Benson Abounu ti wọn jọ figagbaga.
Enugu
Ọjọgbọn Eleazar Ikonne lo bori ninu eto idibo naa.
Oun ni ọga agba fasiti ipinlẹ Abia tẹlẹri.
Delta
Abẹnugan Ile Igbimọ Aṣofin ipinlẹ Delta, Sheriff Oborevwori lo bori ninu eto idibo naa.
Ibo 597 ninu 826 lo fi jawe olubori.
Rivers
Akapo ipinlẹ Rivers tẹlẹri, Fubara Siminialayi lo bori ninu eto idibo naa.
Ibo 721 lo fi jawe olubori.
Akwa Ibom
Komisọnna fun ọrọ ilẹ ati omi tẹlẹri nipinlẹ Akwa Ibom, Pasitọ Umo Bassey Eno lo bori ninu eto idibo naa.
Ibo 993 lo fi jawe olubori.
Saaju ni gomina ipinlẹ Akwa Ibom ti kede rẹ gẹgẹ bi ẹni ti yo rọpo rẹ ti o ba fi ipo silẹ.