Killings and Kidnapping in Anambra: Ìjọba kéde òfin kónílé-ó-gbélé ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́sàn-án

Gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra Ọ̀jọ̀gbọ́n Charles Soludo ti kéde òfin kónílé-ó-gbélé ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́sàn-án.

Ìpinu yìí kò ṣẹ̀yìn àwọn ìpèníjà ìpànìyàn, ìjínigbé àti àwọn nǹkan mìíràn tó ń bá ìpínlẹ̀ náà fínra.

Soludo tó fi àṣẹ náà léde nínú ìkéde tó fi síta lọ́jọ́rú, ọjọ́ Karùndínlọ́gbọ̀n, oṣù Karùn-ún, ọdún 2022.

Ní ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Karùn-ún, ọdún 2022 ní òfin kónílé-ó gbélé náà yóò bẹ̀rẹ̀ láti aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́ sí aago mẹ́fà ìdájí.

Gẹ́gẹ́ bí gómìnà Soludo ti wí, òfin náà de àwọn ọlọ́kadà, kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́ta àti kórópe ní ìjọba ìbílẹ̀ Aguata, Ihiala, Ekwusigo, Nnewi North, Nnewi South, Ogbaru, Orumba North àti Orumba South.

Bákan náà ló ní kò sí ààyè fún àwọn ọlọ́kadà, kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́ta àti kórópe náà láti máa ṣiṣẹ́ rárá ní ọjọ́ Ajé títí di ìgbà kan ná títí ti òfin pé kí àwọn ènìyàn máa jòkòó silé lọ́jọ́ Ajé yóò fi wá sópin.

Soludo rọ àwọn ọ̀dọ́ káàkiri gbogbo àwọn ìjọba ìbílẹ̀ wọ̀nyí láti kún ìjọba àti àwọn òṣìṣẹ́ ètò ààbò lọ́wọ́ láti lè ri wí pé òfin náà fẹsẹ̀ múlẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ náà ló pa á láṣẹ fún àwọn fijilanté láti mú ọ̀kadà àti kẹ̀kẹ́ tó bá lòdì sí òfin náà tábí tí wọ́n bá rí lásìkò tó ń rìn ní àwọn àsìkò tí òfin kónílé-ó-gbélé náà ti bẹ̀rẹ̀.

Ó fi kun pé àwọn adarí àti aláṣẹ ẹgbẹ́ ọlọ́kadà, kẹ̀kẹ́ tàbí kórópe tí wọ́n bá mú ni yóò forí fá ìjìyà ìjọba nítorí náà kí wọ́n fi ẹjọ́ ọmọ ẹgbẹ́ wọn tó bá ń wù ìwà ọ̀daràn tó ìjọba létí kí ọwọ́ tó tẹ̀ wọ́n.

Soludo ní lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì ni àwọn yóò tún òfin náà gbé yẹ̀wò, àmọ́ tí àwọn kò bá rí ìyàtọ̀ àwọn yóò fi òfin dè wọ́n pátápátá.

Ó ní kò sí ààyè fún ìwà àwọn ọ̀daràn láti máa fi ara pamọ́ jẹ àwọn ènìyàn níyà yálà nínú ìgboro tàbí nínú igbó.