Gunmen kidnap priests: Àwọn agbébọn jí fadá ìjọ Kátólíkì méjì gbé ní Katsina

Awọn agbebọn ti ji oluṣọagutan ijọ Aguda meji gbe lẹkun iwọ oorun gusu Naijiria.

Awọn fada mejeeji naa pẹlawọn eeyan meji miran to wa pẹlu wọn ni wọn ji gbe gẹgẹ bi awọn alaṣẹ ijọ Aguda to wa ni Sokoto ṣe sọ fun BBC.

Ni oru idaji Ọjọru ni awn agbebọn ji alufaa meji naa pẹlawọn alejo wọn- arakunrin kan ati aburo rẹ- gbe ni ijọ Aguda St. Patrick Catholic Church, nijọba ibilẹ Kafur nipinlẹ Katsina to wa labẹ akoso daosisi ijọ Aguda Sokoto.

Bi awọn agbebọn ṣe wọ ileejọsin naa

Atẹjade kan ti oludari eto ipolongo ati ibanisọrọ ni daosisi ijọ Aguda lẹkun Sokoto, Ẹniọwọ Chris Ọmọtọshọ fi sita ṣalaye bi awọn ajinigbe naa ṣe kọlu ile ijọsin Aguda St. Patrick Catholic Church, ti wọn si ji awọn fada naa gbe lọ.

"Ni nnkan bii agogo mejila oru oni ọjọ karundinlọgbọn oṣu karun un ọdun 2022, awọn agbebọn fi tipa wọ ile oluṣọagutan ni ijọ Aguda St. Patrick Catholic Church, ni Gidan Maikambo, nijọba ibilẹ Kafur nipinlẹ Katsina.

"Wọn ji oluṣọaguntan ijọ naa ati igba keji rẹ Ẹni ọwọ Stephen Ojapa, MSP ati Oliver Okpara pẹlu ọmọdekunrin kan ati ọmọdebinrin kan ninu ile naa."

Ni bi a ṣe n sọrọ yii, ko tii si iroyin kankan nipa ibi ti awọn mẹrin naa wa tabi ohun ti awọn to ji wọn gbe n fẹ.

Ẹniọwọ Matthew Hassan Kukah ni Biṣọbu agba daosisi ijọ Aguda lẹkun Sokoto, labẹ ẹkun naa si ni awọn ijọ Aguda ni ipinlẹ Kebbi, Zamfara, Sokoto ati Katsina ti iṣẹlẹ naa ti waye wa.

Ki lawọn lọpaa n ṣe bayii lori rẹ?

Ẹniọwọ Ọmọtọshọ sọ fun BBC pe inu ileto kan ni ijọ Aguda naa wa, bẹẹni awọn ọdọ atawọn agbofinro kan ti bẹrẹ si ni wa wọn.

O ni wọn ti fi ọrọ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Katsina, SP Gambo Isah ṣalaye pe lootọ ni wọn ji awọn mẹrin naa gbe.

O ni iwadii ti bẹrẹ lori rẹ.