Oyo APC Governorship primary: Ẹgbẹ́ òṣèlú APC Oyo sún ètò ìdìbò abẹ́nú sí òní, ìdí rèé

Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC ti sún ètò ìdìbò abẹ́nú ẹgbẹ́ náà tó yẹ kó wáyé ní ìpínlẹ̀ Oyo ní ọjọ́bọ̀ ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Karùn-ún sí ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ́n.'

Ní pápá ìṣeré Obafemi Awolowo ni ètò ìdìbò abẹ́nú náà yóò ti wáyé.

Ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìdìbò abẹ́nú èyí tí Tokunbo Afikuyomi ń ṣaájú rẹ̀ ló sún ètò ìdìibò náà síwájú nítorí ẹ̀sùn wí pé àwọn kàn tí kò lẹ́tọ̀ọ́ láti dìbò ti yawọ gbọ̀ngán ibi ètò ìdìbò náà.

Afikuyomi ní ọ̀rọ̀ ààbò náà kún ìdí tí wọ́n fi sún ètò ìdìbò abẹ́nú náà síwájú.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe sọ gbogbo àwọn aṣojú ẹgbẹ́, olùdíje, àwọn aláṣẹ́ ẹgbẹ́, àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ló ti péjú síbi ètò ìdìbò náà kí wọ́n tó sun síwájú.

Ní nǹkan bí aago mẹ́fà ni awọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní kúrò nínú gbọ̀ngàn náà nígbà tí wọ́n ti sún ètò ìdìbò náà.

Àwọn olùdíje mẹ́fà ló ń dupò láti gba àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ìpínlẹ̀ Oyo láti kópa níbi ètò ìdìbò gbogbogboò ní ọdún tó ń bọ̀.

Wo ojú àwọn tó fẹ́ díje dupò gómìnà lábẹ́ ẹgbẹ́ APC ní ìpínlẹ̀ Oyo lónìí

Ko din ni awọn oludije mẹfa ti ṣe afihan ifẹ lati gba tikẹti gomina ti All Progressives Congress (APC) ṣaaju idibo 2023 ni ipinlẹ Ọyọ.

Àwọn mẹ́fà tí ẹgbẹ́ náà ti sàyẹ̀wò náà yóò fà á jáde láàárín ara ni pápá ìṣeré Ọbafẹ́mi Awolowo, Ìbàdàn.

Awon oludije wo lo ra fọọmu APC nipinlẹ̀ Oyo?

Awọn oludije meje ti wọn ra awọn fọọmu naa ni Alagba ti o nsoju agbegbe Oyo Central Senatorial, Teslim Folarin (Ibadan)

igbakeji gomina tẹlẹ (Operations) ti Central Bank of Nigeria (CBN) Oloye Adebayo Adelabu (Ibadan), agba agba ti Nigeria (SAN)

Chief. Adeniyi Akintola (Ibadan) Komisonna fun eto ilera nigba kan ri, Dokita Azeez Adeduntan (Ibadan),

agbẹjọro ilu Ibadan, Barista Akeem Agbaje (Ibadan), Engineer Oyedele Hakeem Alao (Ibadan) ati Alaga, Nigerian Communication Commission (NCC) Ojogbon Adeola Akande