Senegal Fire: Àwọn ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí 11 pàdánù ẹ̀mi wọn lẹ́yìn iná tó ṣẹ́yọ

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Àwọn ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí mọ́kànlá pàdánù ẹ̀mi wọn lẹ́yìn iná tó ṣẹ́yọ.

Ọdun to kọja ni iru iṣẹlẹ naa waye ri ti ẹmi awọn ọmọ jojolo mẹrin lọ lẹyin ti ina jo raurau ni ẹka igbẹbi ni ile iwosan ọhun.

Pẹlu ibanujẹ ọkan ni Aarẹ Ilẹ Senegal, Macky Sall fi ṣalaye pe awọn ọmọ ikoko ti wọn ṣẹṣẹ bi mọkanla ti padanu ẹmi wọn ni ileewosan to wa ni iwọ ọọrun Tiyaouane.

Loju opo ikansiraẹni Twitter ni aarẹ naa ti salaye pe ina bẹ silẹ ni ẹka ileewosan awọn alaboyun ni ileewosan Mame Abdou Aziz Sy Dabakh.

Awọn oloṣelu lorilẹede naa ni waya ina to baj̣e lo fa ina to sọ naa.

Gomina agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye, Demba Diop Sy ni awọn ọmọ mẹta ni awọn ri yọ kuro ninu ina naa.

Mr Say sọ fun awọn oniroyin pe ina naa ja ranyin kaakiri lojiji ni, ti awọn panapana si tiraka lati pa ina naa.

Ileeṣẹ iroyin ti ijọba ni orilẹede naa ni wọn ṣẹṣẹ si ile iwosan naa pada ni.

Ninu atẹjade ti aarẹ naa ti ba awọn eniyan kẹdun lo ti ni akoko to ṣoro ni eyi fun gbogbo eniyan paapaa awọn ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si.

Bakan naa ni minisita fun eto ilera, Abdoulaye Diouf Sarr to n ṣepade lọwọ ni ipade Ajọ Eleto Ilera Lagbaye, WHO ni inu oun bajẹ si iṣẹlẹ naa ti oun si n pada bọ nile lati wa ba awọn eniyan kẹdun.

Amọ awọn oloṣelu ni ẹgbẹ oṣelu miran ti bu ẹnu atẹ lu ijọba pẹlu iwoye pe bawo ni ina ṣe maa si ni ileewosan ijọba.

Ọdun to kọja ni iru iṣẹlẹ naa waye ri ti ẹmi awọn ọmọ jojolo mẹrin lọ lẹyin ti ina jo raurau ni ẹka igbẹbi ni ile iwosan ọhun.

Ti obinrin alaboyun kan si ku toyun-toyun lẹyin to jẹ irora fun ogun wakati, ki o to ṣ̣eṣẹ fẹ se iṣẹ abẹ amọ ati oun ati ọmọ inu rẹ lo gbẹmi mi.