You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ukraine-Russia Crisis: Ìjọba aláṣẹ́ Ukraine ní yóò ṣòro láti mọ ìye èèyàn tó kú torí Russia sì ń yin àdó ikú lọ lágbègbè náà
Awọn alasẹ orilẹede Ukraine ti naka aleebu si orilẹede Russia pe o mọọmọ ba gbọngan nla kan to wa nilu Mariupoli jẹ ni.
Gbọngan naa si ni awọn eeyan to le ni ẹgbẹfa fori pamọ si, ti wọn si n gbe.
Awọn alasẹ ẹka ileesẹ to wa fun ọrọ ilẹ okeere lorilẹede Ukraine lo sisọ loju ajalu nla yii ninu atẹjade kan to fi sita.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ̀jẹ̀ àpọ̀jù tó dà lára Timothy Adegoke torí ọgbẹ́ tó ni ló ṣekú pà á - Onímọ̀ ìwádìí
- Ọ̀kan lára àwọn afurasí mẹ́rin tó gé orí Sofiat Okeowo láti fi ṣẹ́ṣó gba ìtúsílẹ̀
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ní àwọn awakọ̀ èrò fẹ́ ṣe ìwọ́de lónìí l‘Eko torí yíyọ MC Oluomo nípò?
- Kí ló fa rògbòdìyàn tó gbòde ní Ajah, tí ẹ̀mí méjì fi bọ́, tí ọ̀pọ̀ dúkìá sì bájẹ́?
- "Sylvester Oromoni tọ̀ mí wá pé itan ń ro òun kó tó kú, mo sì ba fi ọwọ́ ra á pẹ̀lú òògùn ara ríro"
- Ìwà àtakò sí ìjọba ní bí ọlọ́pàá bá da iṣẹ́ sílẹ̀, kò tọ̀nà - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
- Kò pọn dandan fún akẹ́kọ̀ọ́bìnrin láti lo hijab nílé ẹ̀kọ́ - Ilé ẹjọ́
Ileesẹ naa ni "ado oloro ti ilẹ Russia yin lo ba aarin gbọngan naa jẹ, eyi to mu ki ọpọlọpọ eeyan si sabẹ awoku ile naa."
Bakan naa ni wọn fi kun pe yoo nira lati se odiwọn iye eeyan to fori sọta ikọlu naa nitori bi Russia se n tẹsiwaju lati maa ju ado oloro si agbegbe naa.
Minisita fun ọrọ ilẹ okeere tun ti fi ikede ọhun si oju opo Twitter rẹ.
Amọ ileesẹ BBC ko tii le se iwadii boya lootọ ni aworan keji ti minisita naa fi soju opo rẹ nipa bi wọn se ba gbọngan nla naa jẹ.
Ọ̀pọ̀ òkú ń sùn ní Ukraine, wọ́n ń sin wọ́n ní àsinpọ̀ sí ibojì kan ṣoṣo
Ikọlu ti Russia n ṣe si Ukraine ti lagbara to bẹẹ ti awọn eeyan orilẹ-ede naa ti bẹrẹ si n gbẹ iboji kan ṣoṣo ti wọn sin ọpọ eeyan si bayii.
Ibi ti ikọlu naa ti lagabra julọ ni ilu Mariupol, nibi ti wọn ti gbẹ ọpọlọpọ iboji laarin ọsẹ meji sẹyin.
Igbakeji gomina ilu Mariupol, Serhiy Orlov, ṣalaye fun BBC pe awọn ko le sin oku si ibi ti wọn maa n sin oku si tẹlẹ mọ laarin igboro nitori awọn ọmọ orilẹ-ede Russia ti gba iṣakoso awọn agbegbe naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Afurasí Fulani gé ọwọ́ Fijilańté méjèèjì ni Iwere Ile ni Ipinle Oyo
- Ẹ gbà mi o, àwọn oníjìbìtì ayélujára ti ń bèèrè ìrànwọ́ lórúkọ́ mi - Kemi Afolabi lọgun
- "Ẹgbẹ́ àjẹ́ tí mo wà ní Anambra ló ní kí n pa ọmọ ọ̀gá mi l'Eko"
- Ẹsẹ̀ mi yẹ̀ gẹ̀rẹ̀, mo la orí mọ́ táísì, mo sì fẹ́ ẹ̀ pàdánù ọpọlọ nígbà tà ń ya fíìmù - Mide Martins
- Ẹ wo àwọn obìnrin tí kìí ṣe ọmọ Yorùbá tó jẹ́ ayaba ní ààfin ilẹ̀ Káàárọ̀ oòjíire
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun tẹ afurasí 11 tó dáná sun ọba nílú Agodo
- "Ọ̀pọ̀ èrò ló ń sá padà láti wọnú ọkọ̀ mi torí ń kò ní ẹsẹ̀ méjééjì"
- Ohun tó fa wàhálà Hijab ní Ijagbo rèé - Olùkọ́ àgbà
- Ipò tí Naijiria wà fi hàn pé inú Ọlọrun kò dùn sí orílẹ̀-èdè yìí - Gani Adams
Ṣaaju ni ijọba ipinlẹ ọhun ti kọkọ kede pe o le ni ẹgbẹrun meji eeyan to ti ku ni Maruipol.
Bi ado oloro Russia ṣe n balẹ si Mariupol lemọ-lemọ ko jẹ ko rọrun lati ko awọn araalu jade nibẹ.
Bo tilẹ jẹ pe ọgbẹni Orlov ko le sọ ni pato iye araalu to wa ninu awọn iboji ti wọn sin ọpọ eeyan si, amọ wọn sin oku eeyan mẹ́tàdínláàdọ́rin sinu iboji kan ṣoṣo.
Awọn ẹbi kan si ti n sin oku awọn ara ile wọn si eyinkule wọn bayii.
A ko ni ina, a ko ni omi tabi ounjẹ fun ọjọ mọkanla gbako bayii - Ìjọba
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ni wọn n ṣa oku laarin igboro Mariupol bayii.
Orlov ni awọn mii to lọ n ṣa oku laarin igboro tun fara gbọta ibọn, ti awọn naa si dagbere faye.
O sọ pe "Awọn kan pade iku ojiji lẹyin ti wọn fara gbọta nibi ti wọn ti n lọ ṣa oku laarin ilu."
"A ko ni ina, a ko ni omi tabi ounjẹ fun ọjọ mọkanla gbako bayii."
Wọn gbẹ iboji kan ṣoṣo ti wọn sin ọpọ eeyan si lẹba ile ijọsin kan niluu Kyiv, nibi ti wọn sin ọgọta eeyan si.
Iboji kan ṣoṣo ti wọn sin ọpọ eeyan si ni Ukraine:
Ọjọ Abamẹta ni awọn ọmọ ogun Russia gba agbegbe naa, wọn si kilọ fun awọn dokita ki wọn fi agbegbe ọhun sile ni kankan.
Awọn iboji naa jẹ ohun ibanujẹ ọkan fun ọpọ mọlẹbi ni Ukraine, nitori o mu ki wọn ranti ogun abẹle keji, nibi ti ọpọ awọn ọmọ orilẹ-ede naa ti jade laye.
Omidan kan, Skoryk-Shkarivska sọ fun BBC pe ẹni ọdun méjìléláàdọ́rùn ún ni ẹgbọn iya, o si sọ fun oun pe ogun Russia yii n mu ogun abẹle keji wa si iranti oun.
Skoryk-Shkarivska fi kun pe o ṣe pataki fun ẹbi oun lati sin okun wọn ni liana Kristẹni, pẹlu adura fun oloogbe.
Ni Chernihiv ati Sumy, to wa ni iha Ariwa Ukraine, ni ṣe ni awọn eeyan n ku iku ọwọwọ nibẹ lọwọ ikọlu Russia.
Bakan naa ni awọn ọmọ ogun Russia yi awọn ilu naa ka.
Oleksandr Lomako, to jẹ akọwe ijọba Chernihiv ni ni ṣe awọn eeyan n sin oku si awọn iboji kan fun igba diẹ, pẹlu erongba lati wu awọn oku ọhun lọ si iboji miran ti akoko ba to.
O ni "A o hu awọn oku naa, ki a le lọ sin wọn si iboji ti wọn yoo wa titi ti ogun ba ti pari."