Hirsutism: Wo ohun tí ojú obìnrin tó ní irun ní gbogbo ara ń rí torí ó dà bí ọkùnrin

Ara meeriri lo maa n jẹ ni ọpọ igba, tawọn obinrin maa n ni irun lara bii ti ọkunrin, tori awọn ọkunrin lo maa n saaba ni irun ni oju ati gbogbo ara.

Amọ arun kan wa ti wọn n pe orukọ rẹ ni 'Hirsutism' eyi to maa n mu ki eroja ara ọkunrin maa peleke lara obinrin.

Awọn eroja yii lo maa n mu irun ara ọkunrin jade lawọn agbegbe ti ọkunrin ti maa n ni irun lara bii aya, ẹsẹ ati ẹyin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iru arun yii gan an ni ọmọ ọdun mọkandinlogun, Nwaonicha-Emeghani Chidube, ọmọ orilẹede Naijiria ni.

Chidbe ni ''ariyanjiyan kan waye laarin emi ati ọmọkunrin kan, lo ba pe mi ni "Ọgbẹni".

O dun mi gan an, bi gbogbo eeyan ṣe n pe mi ni 'Ọgbẹni' niyẹn.

Ṣugbọn mo padi ọrọ da fun un: mo ni bi o ba n pe mi ni ọkunrin, jẹ ka jọ ja bi ọkunrin nigba naa."

Ki lo n fa irun pupọ lara obinrin bii ti ọkunrin?

Lara awọn ohun to n fa arun yii ni ohun tawọn onimọ iṣẹgun oyinbo n pe ni polycistic ovary Syndrom (PCOS), Cushing's syndrome,

Ati lawọn igba kọọkan, o le jẹ eewo jẹjẹrẹ ti a mọ si 'tumour.'

Nigba ti Chidube pe ọmọ ọdun mẹrindinlogun lo kọkọ bẹrẹ si nii ṣe akiyesi irun to n hu lawọn agọ ara rẹ kan.

O kọkọ ba ni lẹru gan, PCOS kii ṣe ohun ti o kan le ṣadeedee ni, ki o si foju foo.

''Ọpọ igba ni mo maa n ro o pe ṣe mo maa le bimọ bayii?"

"Nigba wo ni maa dẹkun ati maa sanra tabi ga sii?"

Koda nigba ti mo wa nileewe girama, mo maa n rii daju pe mo ge gbogbo irun mi lọsọọsẹ

Ọgbẹ abẹ a wa kun gbogbo ọrun mi, maami a wa maa sọ fun mi pe:

" Ma da ara rẹ laamu". Igba ti mo gbe aworan kan soju opo instagram ni mo to bẹrẹ si ni gba bi mo ṣe ri.

Ibẹrẹ ọdun yii niyẹn, ṣaaju, oju maa n ti mi lori rẹ ni.

Wo ipenija tawọn obinrin to ni apọju irun lara maa n koju:

Ọpọlọpọ awọn ọmọbinrin ni wọn maa n kan si mi lati ọpọlọpọ awọn orilẹede lati sọ bi ti wọn ṣe ri.

Wọn a sọrọ nipa bi awọn ọkunrin ṣe n ja wọn silẹ nitori bi ara wọn ṣe ri, mo wa di ọlọrẹ pupọ.

Ọkan mi wa maa n balẹ ti mo ba ti wa n gbọ awọn ọrọ wọnyii, ti mo si tun n mọ awọn eeyan sii.

Emi nikan kọ ni o n ni idojukọ yii, awọn obinrin miran bẹẹ naa wa.

Awọn arẹwa obinrin to n la nnkan bayii kọja.

Emi nikan ni ọmọbinrin to ni irun lara laarin ọpọlọpọ eeyan.

Mo wa maa n ri ara mi gẹgẹ bi eeyan pataki nitori awọn eeyan n wo mi ni awoyanu.

Wọn a maa sọ pe ọmọbinrin yii ni irun lara.

O jẹ ohun to maa n mu mi wo ara mi gẹgẹ bi eniyan ọtọ, nibi kibi ti mo ba wa, awọn eeyan maa n mọ.

A gbọdọ gba ara wa gẹgẹ bi a ṣe ri gẹgẹ bi obinrin. Eeyan ọtọ ni wa.

Oniruuru ẹya, iwọn ati ipo ni a ba wa saye, eyi si lee jẹ ibukun fun wa,'' Chidube lo sọ bẹẹ.