You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Zambia Pastor: Èèyàn márùn-ún di èrò ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tí wọ́n sin wòlíì láàyè lásìkò ètò àdúrà
Ara meeriri, mo ri ori ologbo lori atẹ ni ọrọ isẹlẹ kan to waye nigba ti wolii kan ni ki awọn ọmọ ijọ rẹ sin laaye, ki oun si pada jinde, amọ to gba ibẹ ku fin-fin.
Idile ẹlẹni marun kan lo pe wolii wa sinu ile wọn lati wa se isẹgun fun wọn to wa ni abule Mazonde, lorilẹ-ede Zambia, lati le awọn ẹ̀mí buburu jade.
A gbọ pe ni ṣe ni Wolii Shamiso Kanyama sọ fun awọn ọmọ ẹyin rẹ pe ki wọn o sin oun laaye, ki oun ba le ke pe awọn agbara ìwẹ̀nùmọ́ ti yoo wo ẹbí naa ṣàn kuro lọwọ agbara ati airi to n pa wọn ni ipakupa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọmọ ìyá méjì tó ń lọ ṣe ìdánwò NECO wà lára èèyàn márùn ún tí tírélà agbépo tẹ̀ pa n'Ibadan
- Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí wọ́n ó fi Chidinma Ojukwu tí wọ́n lo pa Ataga sí ẹ̀wọ̀n
- Ajínigbé yìnbọn pa ọkọ, jí ìyàwó àti ọmọbìnrin rẹ̀ gbé lọ l'Ekiti
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni ìbálòpọ̀ lásìkò nǹkan oṣù lè ṣekúpa ọkùnrin?
- Babaláwo fi ọ̀dọ́ tó fẹ́ ṣe òògùn owó, ṣe ètùtù owó fún ara rẹ̀
- Ìdí rèé táwọn ọmọlẹ́yìn Igboho méjìlà fi wà láhámọ́ títí di ọjọ́ Ajé - Amòfin Yomi Aliyu
- Wo ìgbésẹ̀ tuntun tí DSS ń gbé láti dojú béèlì àwọn ọmọlẹ́yìn Igboho méjìlà bolẹ̀
- Ọwọ́ FBI yóò tẹ Abba Kyari, òǹyẹ̀ kankan kò lè yẹ̀ ẹ́ - Femi Falana
- Akeugbagold sọ̀rọ̀ lórí bóyá ṣíṣe àjọ̀dún Hijra tọ̀nà àbí bẹ́ẹ̀kọ́ pẹ̀lú ìkéde ọjọ́ ìsinmi
Lẹyin naa lo darapọ mọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ lati gbẹ ibojì to fẹ ki wọn o sin oun si.
Ṣe ẹni ba rán ni nisẹ laa bẹru, a kii bẹru ẹni ti a o jẹ ẹ fun, n se ni àwọn eniyan naa ṣe bi Ọga wọn ṣe sọ, lẹyin to gbadura, to si bẹ sinu iboji fúnra rẹ, wọn ko iyẹpẹ le e lori bi oku.
Sugbọn ọrọ gba ibomiran yọ nigba ti awọn ọkunrin naa pada gbẹ iboji naa lati wo o boya wolii ti jinde bo ṣe sọ, oku rẹ ni wọn ba.
Wọn ti wa fi ẹsun ipaniyan kan eeyan marun-un ninu ẹbí naa lẹyin ti wolii naa, ti wọn pe si ile wọn fun eto adura, jade laye.
Awọn iwe iroyin abẹle nibẹ sọ pe, awọn afurasi marun-un naa farahan niwaju ile ẹjọ giga kan ni Harare, fun ẹsun pe wọn lọwọ si iku wolii Shamiso Kanyama, lasiko to n sisẹ iṣegun fun wọn.
Ẹnikan to rojọ tako àwọn eniyan naa nile ẹjọ, Father Zvidzai sọ pe, lootọ ni wolii naa ṣe bẹẹ, sugbọn oun gbiyanju lati da awọn eniyan naa duro nigba ti wọn bu iyẹpẹ diẹ le e lori, àmọ́ wọn ko gbọ.
"Mo kilọ fun awọn ọkunrin naa pe o lewu láti sin eeyan laaye, sugbọn wọn ko gbọ.
Koda, Wolii Kanyama pariwo mọ mi pe mo n di àwọn angẹli oun lọwọ, to si ni ki wọn o tẹsiwaju lati ma a rọ iyẹpẹ sinu iboji naa."