Prophet Shittu Adeniyi: Ẹni tó bá ń tọrọ agbe, kìí jẹ́ èèyàn ní mo ṣe tẹ́pa mọ́ṣẹ́

Yoruba ni bi ẹmi ba wa, ireti n bẹ, ẹda ko si ni aropin.

Eyi ni imọran ojisẹ Ọlọrun kan to ni ipenija oju, Wolii Shittu Adeniyi, ti ọpọ eeyan mọ si Wolii Oluwalogbon, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori awọn ohun to n la kọja ati iriri to ni nile aye.

Ninu ọrọ rẹ, Wolii Oluwalogbon ni oun padanu oju oun lẹyin osu mẹta ti iyawo oun jade laye lọjọ to bi ọmọ tuntun.

Nibayii, ojisẹ Ọlọrun naa ti fẹ iyawo miran, bi awọn ọmọ, o n kọrin, se ọsin ẹja, to si tun n ya fiimu pẹlu.

Wolii Shittu Adeniyi wa rawọ ẹbẹ sawọn eeyan to ni ipenija ara bii tiẹ lati mase sọ ireti nu, tabi ro ara wọn pin.

Bakan naa lko rọ wọn lati gbara le agbe sise nitori ipo ti wọn wa, amọ ki wọn wa isẹ oojọ kan se nitori o ni ẹni to ba n se agbe jẹun, kii jẹ eeyan gidi laye.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: