You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Church of Satan: Báwo ni ìjọ́sìn ṣe n rí nínú ìjọ Sátánì?
Laipẹ yii ni ile ẹjọ giga ti ijọba apapọ Naijiria, to wa ni ilu Umuahia nipinlẹ Abia, gba oniduro oludasilẹ ijọ Satani, Ifekwe Udo.
Oun ati awọn mẹtadinlogun miran, ni awọn ọlọpaa mu nitori ija igboro to waye ni Ebem Ohafia.
Awọn ara ilu naa fi ẹsun kan Udo ati ijọ rẹ pe, apẹẹrẹ buruku ni wọn jẹ fun ilu naa, ti wọn si ba awọn dukia ijọ naa jẹ.
Lara ẹsun ti awọn araalu tun fi kan an ni pe, o n da alaafia ilu naa ru.
Koda, ijọba ibilẹ naa ti sọ pe ko tun gbọdọ ko ijọ rẹ jọ mọ ni ilu naa, nitori pe o n ta epo si aṣọ àlà ilu naa.
Ijọ wo gan-an ni 'Church of Satan'?
Ọgbọnjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 1966 ni wọn da ijọ Satani silẹ, lati ọwọ Anton Szandor LaVey, nilu San Francisco l'orilẹ-ede America.
Gẹgẹ bi akọsilẹ to wa ni itakun agbaye ṣọọṣi naa, oun ni ipejọpọ akọkọ to n gbe igbe aye rẹ gẹgẹ bi ẹlẹran ara.
Fun awọn olujọsin, wọn ko sin Satani, ṣugbọn wọn ri i gẹgẹ bi apẹẹrẹ to ba iru eeyan ti wọn jẹ mu nipa ìbí.
Wọn sọ pe esu duro gẹgẹ bi awokọṣe fun igberaga, ominira, ati gbigbe igbe aye ẹni lọna to wu ni - awọn amuyẹ ti awọn kan n pe ni iwa buburu.
Igbagbọ awọn ọmọ ijọ Satani ni pe eniyan, nipa ọgbọn inu rẹ, lo da gbogbo awọn ọlọrun ke ke ke.
Ẹnikẹni to n sin iru awọn ọlọrun bẹ ẹ, ẹni to da a ni wọn n sin.
Ko tan sibẹ o, awọn ọmọ ijọ Satani sọ pe awọn ni ọlọrun ara wọn.
Ati pe awọn n fi ifẹ han si ẹni to ba tọ si, ati ibinu si ẹni to ba mu inu bi wọn, tabi tapa si igbagbọ wọn.
LaVey gbagbọ pe, Ọlọrun awọn Kristiẹni ko ni òye tabi ni imọ nipa bi ko ṣe rọrun lati jẹ eniyan ẹlẹran ara.
O si pinnu lati fi opin si "iye rira, ati abosi, ti awọn ṣọọṣi ẹsin Kristiẹni n polongo".
Ati nnkan ti yoo mu ki awọn eeyan ni ominira lati lo agbara okunkun fun ifẹ ara wọn.
Oriṣa kan to si farajọ iru nkan to fẹ ni Satani - "ẹda to n fun ni ni èrè to yẹ.
Ẹni to jẹ pe dipo ki o dá ẹṣẹ, ki ẹri ọkan o le ma a jẹ awọn eeyan, o kuku fi aaye gba titẹ ifẹ ara ẹni lọrun.
Oun nikan ni oriṣa ti ọrọ wa ye."
Ibẹrẹ ijọ Satani:
Lati nkan bi ọdun 1950, ni awọn to faramọ erongba LaVey ti n sun mọ ọ, nipa kikorajọ pọ si ile rẹ "Black House" nilu San Francisco.
Awọn iwadii ti LaVey ṣe nipa ẹmi okunkun, lo pilẹ bi wọn ṣe n lo ẹgba ọrun dudu ati pupa, to ni aworan ẹyẹ àdán.
Ṣọọṣi naa tun sọ pe lẹyin ọdun diẹ, LaVey bẹrẹ si iṣẹ idán okunkun ati agbara irubọ, o n ṣe nipa igbega lẹni iṣẹ, ẹbun ọfẹ, owo, adun ibalopọ, ati pipa tabi yanju awọn ọta rẹ.
Eyi lo tubọ mu ki ọpọ eeyan sun mọ, nitori wọn gbagbọ pe, o ti ni aṣẹ Agbara Okunkun Aye.
Laarin ọdun kan aabọ ti wọn da ijọ Satani silẹ, ẹẹmẹta ni ariwo sọ lori rẹ ninu awọn iwe iroyin.
Igba akọkọ ni ti igbeyawo to waye laarin gbajugbaja akọroyin kan, John Raymond, ati Judith Case, ọmọ gbajugbaja agbẹjọro.
Awọn mejeeji lo jẹ ọmọ ijọ, ti wọn si kesi Olori Alufaa wọn, LaVey lati so wọn pọ ni orukọ Satani.
Gbogbo ileeṣẹ iroyin nilẹ America, to fi de Europe lo fẹ ẹ ni aṣoju nibi eto igbeyawo naa, lati kọ nipa ara meeriri igbeyawo ọhun.
Ipele àṣẹ ninu ijọ Satani:
Ọmọ ijọ to f'orukọ silẹ
Ọmọ ẹgbẹ to n ṣe deede (Oye Akọkọ)
Ajẹ/Oṣo (Oye keji)
Alufaa ọkunrin/obinrin (Oye kẹta)
Magistra/Magister (Oye kẹrin)
Maga/Magus(Oye Karun un)
Ilana Ijọsin wọn:
Irubọ wọn akọkọ jẹ iṣọtẹ si ẹsin Kristiẹni. N ṣe ni wọn sẹ pẹpẹ obinrin to wa ni ihoho, pẹlu orin ikọkukọ.
Koda, wọn dori agbelebu kodo, ti wọn si ka Adura Oluwa lati ipari.
'Omi mimọ' ti wọn gbe kalẹ ni wọn sọ di aimọ, nipa kiki nkan si oju ara obinrin.
Ọti wiski ni wọn fi jẹ ounjẹ alẹ Oluwa dipo ẹjẹ Jesu.
Awọn orukọ oriṣa ni wọn si n pe, dipo orukọ Ọlọrun awọn Kristiẹni.
Igbakeji ni asiko ti LaVey ṣe iribọmi fun ọmọ rẹ obinrin ni ilana Satani.
Dipo riri ọmọ naa sinu omi, ẹnu ọna pẹpẹ ijọ ni ọmọ naa joko si, pẹlu oriṣiriṣi nkan ti ẹnu n jẹ.
Bakan naa lo wọ koto to ni aworan Satani si ori, to si ka oriṣiriṣi ọrọ lati jẹjẹ atilẹyin ati ifọkansi fun Satani.
Ọpọlọpọ wọn ko sin Satani:
Iyalẹnu to wa nibẹ ni pe ọpọlọpọ awọn to jẹ olufọkansin ninu ijọ naa kii jọsin fun Satani - wọn ko gbagbọ ninu ọlọrun kankan.
Wọn ko tako ṣiṣe ọdun Keresimesi:
Iyalẹnu nla ni eyi jẹ lati ri i pe wọn faramọ ṣiṣe ajọyọ ọjọ ibi Jesu.
Igbagbọ wọn nipe lọwọ awọn ẹlẹsin ibilẹ ni awọn Kristiẹni ti ja akoko ayẹyẹ naa gba.
Ṣugbọn ṣa, Baba Keresi jẹ ọna lati dun ara ẹni ninu, eyi to jẹ ọkan pataki lara afojusun wọn.
"Ni asiko yii, a n gbadun adun aye, a si wà pẹlu awọn ti a fẹran."
O ko le ri ijọ Satani kankan ni agbegbe rẹ:
Gẹgẹ bi o ṣe wa lori itakun agbaye wọn, ijọ Satani ko ni ile ijọsin kankan, nitori pe "o tako ilana ti ẹnikọọkan wa n gba lo igbeaye wa.
Yatọ si ile oludasilẹ rẹ, ti wọn ti bẹrẹ ijọ naa, wọn ti fi igba kan ni awọn ẹka ile ijọsin , ṣugbọn wọn ti tu wọn ka, nigba ti wọn ro o pe ko ba oju mu.
Koda, Olu ijọ naa ti kuro ni ile LaVey ni San Francisco, o si ti wa ni ilu New York.
Wọn ko si fi aaye silẹ fun ẹnikẹni lati ṣe abẹwo si ibẹ.
Ida kọnkọ si ni wọn ti maa n ṣe awọn ayẹyẹ wọn.
Diẹ lara awọn ilana wọn ni pe:
Ti alejo nile rẹ ba mu inu bi ọ, huwa si i laini aanu
Ma ṣe ni ibalopọ ti ẹni naa ko ba fi ami han pe, oun fẹ ẹ ba ọ lopọ
Ma ṣe pa awọn ọmọde lara
Ma ṣe pa ẹranko, ayafi fun ounjẹ rẹ tabi ti o ba doju ija kọ ọ
Ma ṣe wa ija ẹnikẹni, ṣugbọn o le pa ẹni to ba wa ija rẹ run, lẹyin ti o ba ti kilọ fun.
Awọn nkan ti wọn ka si ẹṣẹ ni jijẹ omugọ, imọ tara ẹni nikan, ki eeyan o ma a dibọn, titan ara ẹni jẹ, aini
Ijọ naa tako lilo, ati katakara oogun oloro.
Wọn gbagbọ pe ọmọ ijọ to ba tako ofin to de oogun oloro ni orilẹ-ede rẹ, ṣe e si iparun ara rẹ.
Ijọ Satani kii ṣe fun talika:
Igba ati marundinlọgbọn Dọla (N81,000) ni ọmọ ẹgbẹ tuntun ma n san lati darapọ.
Eyi si da lori bi ẹni naa ba ṣe le dahun awọn ibeere ti wọn ba bi i.
Igbakuugba si ni wọn le fi opin si jijẹ ọmọ ẹgbẹ fun ẹni naa.