Church of Satan: ọ̀rọ̀ Femi Fani-kayode fàbínú àwọn ọmọ ìjọ yọ

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

'Satani wa kọ́ ló ń yọ Nàìjíríà lẹ́nu o'.

Awọn ọmọ ìjọ Sàtánì tí bẹ̀rẹ̀ sí ni bínu sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lóri ọ̀rọ̀ kan ti Femi Fani-Kayode sọ tó si ń dà èbi ru Sàtánì nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, láwọn ọmọ ìjọ̀ Sàtánì bá fárígá.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Wọn ni gbgobo ọ̀rọ̀ tó bá tó ba ti jọ mọ́ ǹkan ti kò dára ní wọn máa ń da ẹ̀bi rẹ̀ ru Sàtánì; bẹẹ Satani ti àwọn n sìn kìí ṣe buruku.

Mínísítà, fún ètò ìrìnnà orí afẹ́fẹ́ tẹ́lẹ̀ ri, Femi Fani-Kayode, ló fa ìbínú wọn yọ nígbà tó ń bú adelé ààrẹ ọjọgbọn Yemi Osinbajo pé ọmọ iṣẹ́ Sàtánì ni.

Femi Fani-Kayode tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ alátakò People's Democratic Party (PDP), sọ pé Ọ̀jọ̀gbọ́n Osínbajo ò yẹ lẹ́ni to lè bẹnu àtẹ́ lu àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó hùwà àjẹbánu ni orílẹ̀-èdè yìí nítorí òun gan-an tí dalẹ̀ àwọn àwọn ọmọlẹ́yìn Kírístì

Ọ̀rọ̀ ti Fani Kayode so lórí òpó twitter rẹ̀ tó fa ìbínú tí ìjọ Sàtáni tó ti bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1966 nìyìí:

Ó sọ̀rọ̀ náà nígbà tó ń fèsì sí ọ̀rọ̀ ti Osinbajo sọ láti tako àwọn olùsọ àgùntan tí wọn ni àwọn tako ìgbógun ti ìwà àjẹbanu ti ìjọba àpapọ̀ ń jà àti pé àwọn kìí wàásù lòdì síi.

Ohun tó tún dá kún ìsòro yìí pàápàá ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni pé wọn ti dá ààrẹ Buhari lóhùn nígbà kan ri lórí àtẹ̀jíṣẹ́ twitter rẹ lẹ́yìn tó dárukọ Sàtánì.