You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn opó 150 gba irinṣẹ́ ọrọ̀ ajé nílú Ìwó
"Ohun ti awa opo n dojukọ lawujọ kii ṣe kekere rara. Ọpọ to ri nkan mu ṣe ọrọ lawujọ ni kii ranti awa opo."
Eyi ni ipe awọn opo nipinlẹ Ọṣun lasiko ti awọn aadọjọ opo kan n tẹwọ gba ohun elo amayedẹrun nipinlẹ Ọṣun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Awọn ohun elo iṣẹ alabọde bii ẹrọ ilọta, ẹrọ guguru, ẹrọ iṣerun, ẹrọ iranṣọ, ati owo lati fi bẹrẹ iṣẹ kereje-kereje ni awọn opo naa tẹwọ gba nibi eto kan ti ajọ kan ti kii ṣe tijọba gbe kalẹ ni ilu Iwo.
Diẹ lara awọn opo naa to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe awọn opo n dojukọ ipenija to pọ lawujọ.
Arabinrin Toyin Tijani ninu ọrọ rẹ ṣalaye pe, 'ọpọ awọn opo lo n da bukata atijẹ ati atimu ọmọ wọn gbọ.'
Gbogbo awọn opo miran nibi eto naa to janfani awọn ohun elo naa bii arabinrin Racheal Taiwo ati Kudirat Rufai ni awọn ohun elo iṣẹ kerejekereje ti wọn fun awọn 'yoo wulo lati da ileeṣẹ alabọde silẹ lati maa bọ ẹbi awọn.'
Ninu ọrọ rẹ, alakoso eto igbayegbadun fawọn opo naa, Amofin Funmi Lamuye ni asiko to fun awọn ti eledumare ba ṣẹgi ọla fun lawujọ lati maa ranti awọn to ku diẹ kaato fun, paapaa julọ awọn opo.
"Ohun ti mo fẹ lati ọdọ awọ opo wọnyi ni pe ki wọn maṣe ta awọn irinṣẹ ti a gbe le wọn lọwọ yii nitori eredi rẹ ni lati ṣan ọna atijẹ ati atimu funwọn, o si yẹ ki wọn loo bẹẹ gẹgẹ."