You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Marriage Certificate: Bí o ṣe lè mọ ìgbéyàwó tí kò bá òfin mu
Ibi ijọsin irinwo le mẹrinla (314) nikan lo niwe aṣẹ lati ṣegbeyawo ki wọn si fun ni ni iwe ẹri.
Nibi ti wọn ti n ṣe ipade apero kan nipa ilana ti wọn fi n ṣe igbeyawo lọna ofin lorilẹede yii ni akọwe agba ile iṣ to n ri si ọrọ abẹnu, Georgina Ehuriah ti lede ọrọ naa.
Nitori naa bi o ko ba ṣe igbeyawo nibi to ni iwe aṣẹ, o lee wọ pegé bii igba ti o ba fẹ gba iwe irina loke okun tabi bi o ba fẹ gba oku ọkọ tabi aya to papoda tabi nkan ini wọn.
Arabinrin Ehuriah sọ fun BBC pe "ojoojumọ ni iru nkan bayii n ṣẹlẹ to ṣe pe tọkọ taya yoo fẹ rinrinajo lọ oke okun to si ṣe pe iwe ti ṣọ́ọ̀ṣì ti ko láṣẹ fun wọn ni wọn yoo na siwaju".
O ṣalaye pe nibi ifọrọwanilẹnuwo fun irina wọn loju ọpọ ti maa n ja a ti ile iṣẹ afọrọwanilẹnuwo "embassy" ko ni gba eyi ti wọn mu wa iyẹn ti abẹle ni Naijiria eyi ti wọn n pe ni "form E".
Bakan naa, bi ọkọ tabi aya kan ba ku ti ẹni keji si fẹ gba nkan ini rẹ, o ti di ọrọ rẹpẹtẹ tori oo ni le ri yanju. "Eyi lo n mu ki awọn eeyan sọji lati maa tete lọ si ile ẹjọ ti ijọba lati lọ ṣe igbeyawo ki a to gbe ara wa lọ si ṣọọṣi lati fi ibunkun de e lade tori ẹsin ṣe pataki si wa gẹgẹ bi ọmọ Naijiria.
Ẹwẹ, ireti wa fun awọn ti ko tii ṣe igbeyawo atawọn ti ko da loju pe ojulowo ni igbeyawo awọn.
Awọn Iroyin mii ti ẹ le nifẹ sii
- Barrister ló sọ mí di èèyàn ńlá - Ayinla Kollington
- Ìtàn tó wà nídi òwe ‘Sebótimọ Ẹlẹ́wà Sàpọ́n’
- Ìtàn tó rọ̀ mọ́ òwe ‘aṣọ kò bá Ọ́mọ́yẹ mọ́...’ rèé
- Afọnja, ẹni tó finú wénú ní Ilọrin, àmọ́ tó jẹ iwọ
- Ẹfunsetan Aniwura, obìnrin tó ju ọkùnrin lọ
- Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn, Aláàfin obìnrin àkọ́kọ́ rèé, tó ní nǹkan ọkùnrin
Akọwe agba ni "o ni ibi ti ẹ le lọ loju opo ayelujara ile iṣẹ to n ri si ọrọ abẹnu lati wo o boya ijọ yin ni iwe aṣẹ".
Ṣugbọn o ni, ko wa tumọ si pe ohun gbogbo ti bajẹ o, tun lee pada lọ si oju opo kan naa lati kọwe ranṣẹ pe ẹ fẹ gba iwe ẹri igbeyawo".
Arabinrin Ehuriah ni awn ile ijọsin Kristẹni lawọn maa n sába fun ni iwe ẹri ṣugbọn awọn agbo mii ko si ninu iwe ofin to ni ṣe pẹlu igbeyawo to faaye gba ọkọ kan ati aya kan.