Adekunle Gold: Ọdún márùn ún ni mo fi mọ Simi ká tó ṣègbéyàwó

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Orin ẹ ku oriire ati eyi wuwa lawọn ololufẹ awọn gbajugbaja olorin takasufe Adekunle Gold ati Simi n kọ si orin tuntun ti awọn mejeeji gbe jade lati fi ṣami igbeyawo wọn to waye laipẹ yii.

Orin ọhun eyi ti wọn pe akọle rẹ ni "Promise" ni wọn gbe jade sori ikanni twitter ati youtube eyi ti awọn ololufẹ wọn si ti n kan saara si wọn lorii rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọpọlọpọ awọn ololufẹ awọn akọrin naa ni wọn n woye nigbati iroyin jade pe igbeyawo wọn yoo waye ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ nigba ti wọn fi eto igbeyawo naa ṣe bonkẹlẹ.

Amọṣa ninu iwe kan ti awọn iwe iroyin lorilẹede Naijiria gbe jade pe akọrin 'Orente' naa fi iroyin kan sita pe

'Ṣaaju ni ọdun 2018, mo ke si afẹsọna mi ọdun marun pe ko wa di iyawo mi. Pẹlu pe o mọ gbogbo aiṣedede mi, o jẹ mi ni oo!'

Adekunle Gold ni ọdun marun sẹyin ni oun ti mọ Simisọla Bọlatito Ogunlẹyẹ ti ọpọ mọ si "Simi"

O ni idi ti awọn fi ṣe igbeyawo awọn ni bonkẹlẹ ni wi pe, kii pẹ ti afẹfẹ ilumọọka maa fi n gbe eniyan lọ, nitori naa ni awọn fi fẹ jẹ ki igbeyawo ati igbe aye awọn o wa ni bonkẹlẹ.

Ohun kan to tun da yatọ ninu fọran fidio orin naa ni bi wọn ṣe lo awọn eto ayẹyẹ igbeyawo wọn ninu rẹ.

Bi awọn kan to ti ṣe iyawo tẹlẹ ṣe n pariwo pe orin naa ati ajọṣepọ awọn mejeeji ki wọn to di lọkọlaya mu ori awọn wu, igbeyawo wọn pẹlu ko si ja wọn kulẹ

Ohun ti awọn miiran n sọ ni pe orin yii ni orin igbeyawo ti awọn lọkọlaya to ba fẹ ṣayẹyẹ igbeyawo lọdun 2019 yoo maa lo.