Male infertility: N kò lè ṣe gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin, ṣùgbọ́n n kò mọ̀ títí tí mo fi ṣe ìgbéyàwó

Àkọlé fídíò, N kò lè ṣe gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin, ṣùgbọ́n n kò mọ̀ títí tí mo fi ṣe ìgbéyàwó

Oriṣiiriṣii arun ni o wa ni duniyan, ki Eleduwa maa fi aisan ṣe wa tọmọ tọmọ ki o fawọn to wa ni idubulẹ aisan ni alaafia to peye.

Ọkunrin kan, ẹni ọdun marunlelọgbọn lo pariwo sita pe oun ko le ṣe gẹgẹ bi ọkunrin bo tilẹ jẹ pe o ni iyawo nile.

Ọkunrin ko tilẹ mọ pe oun ni iṣoro yii to fi ṣe igbeyawo nitori nkan ọkunrin rẹ maa n gberi ṣugbọn kii damira ni iṣoro to wa nibẹ.

Igba ti o mọ pe oun ni iṣoro yii asiko to ni ibalopọ pẹlu iyawo rẹ.

Nigba naa ni iyawo rẹ pe akiyesi rẹ pe ko damira lasiko tawọn jọ ni ibalopọ eleyii to ya ọkunrin naa lẹnu.

Lẹyin ọpọ ayẹwo ti o ṣe ni o to mọ pe arun tọ ṣuga to ti wọ ọ lara lo ṣokunfa aisan ti wọn n pe ni ''retrogade ejaculation'' eyi ti o ba a finra.

Ọkunrin yii pada sọ fun iyawo rẹ pe o le lọ fẹ ọkunrin mii tawọn ko ba le bimọ ti oun ba fi pe ọdun marunlelọgbọn.

Ọkunrin yii n beere fun iranwọ awọn ẹlẹyinju aanu lati le ṣe itọju ara rẹ.