Kola Tubosun: Ọ̀pọ̀ ọmọ òyìnbó ló ń kọ́ èdè Yorùbá, ẹ̀yin ọ̀dọ́ ẹ gbé èdè abínibí lárugẹ
Onimọ nipa ede Yoruba kan, to tun n kọ awọn akẹkọọ fasiti ni ede Yoruba lorilẹ-ede AMẹrika, Kola Tubosun ti ke si awọn ọdọ lati gbe ede abinibi larugẹ.
Tubosun, ẹni to ti tumọ ọpọ ewi lede oyinbo si ti Yoruba lo kede bẹẹ lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori bi ede abinibi wa se n wọọkun.
Bakan naa lo ni o yẹ ki gbogbo ọmọ Yoruba gbe ede wọn larugẹ niwọn igba ti awsn ọmọ oyinbo n laagun lati gbọ ede abinibi tiwa.
O fikun un pe ta ba sọra, afaimọ ko ma jẹ pe awọn ọmọ oyinbo ti oun n kọ nisẹ, ni yoo pada wa maa kọ awọn ọmọ wa ni amulo ede Yoruba pada.
Onkọwe ati atumọ ede naa tun rọ awọn ọmọ Naijiria lati mase maa fi oju abuku wo aarẹ wa, to ba gba lati fi ede abinibi wa sọrọ ni ipade awọn orilẹede lagbaye.
- Ambọde f'agbara fun ede Yoruba
- Àmì ohùn yìí yi bóbó lẹ́nu wọn
- Kini Yoruba ‘International passport’?
- Ẹ sọ èdè Yorùbá kíkà di kàńpá níléẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ̀rẹ̀ àti girama - Ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè
- Yorùbá rẹwà, kọ́ nípa àwọn ọ̀rọ̀ tí ìró ẹnu wọn jọra àmọ́ tí ìtumọ̀ wọn yàtọ̀
- Ọmọ tí wọ́n bá fi èdè Yorùbá kọ́ ní ẹ̀kọ́ máa ń pegedé jú tí èdè míràn lọ- Ọjọgbọn Ogundeji
- Ó ṣe mí ní àánú fún ọmọ Yorùbá tí kò le sọ èdè abínibí rẹ́ - Ọmọ Igbo Chukwuka
- Gani Adams gb'oriyin fun'pinlẹ Eko
Kola Tubosun wa gba ijọba nimọran lati gba awọn olukọ laaye lati maa fi ede abinibi kọ awọn akẹkọọ, ki eto ẹkọ kikọ le ye wọn daadaa.
Bakan naa lo kede pe ki wọn fun awọn akẹkọọ jade nile ẹkọ girama laaye lati maa fi ede abinibi kọ awọn idanwo asejade bii WAEC ati JAMB.




