Bí àlááfíà yóò ṣe wà láàrin Fulani àti Yorùbá ni Ooni bá lọ sọ́dọ̀ Buhari- Ààfin Ile Ife

Àkọlé fídíò, Bí àlááfíà yóò ṣe wà láàrin Fulani àti Yorùbá ni Ooni bá lọ sọ́dọ̀ Buhari- Ààfin Ile Ife

Aafin Ile Ife ti ṣalaye idi abajọ ti Ooni Ile Ife, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi fi ṣabẹwo si Aarẹ Muhammadu Buhari lori aawọ to wa laarin awọn Fulani atawọn agbẹ nilẹ Yoruba.

Agbẹnusọ fun Ooni, Moses Olafare sọ fun BBC Yoruba pe Ooni sọ fun Buhari lati wa nkan ṣe si ọrọ awọn Fulani kan to huwa ọdaran nilẹ Yoruba ni.

Ọgbẹni Olafare fikun ọrọ rẹ pe Ooni gbọingbọin ni Kabiyesi wa lẹyin Sunday Igboho, amọ ọba laye gbọdọ pẹtu si ija ni nitori ko si ọba to maa fẹ ki ilu tu mọ ọ lori.

Ọlafare ko ṣai kilọ fun Igboho pe ki ijimere rẹ ṣogi gun, ko maa ba gun igi aladi.