You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ibadan Violence: Ṣé lóòtọ́ ní àwọn jàǹdùkú jó ìlé 200 àti ọ̀kọ́ 29 ní Ibadan?
Laipẹ yii ni iroyin fi lede wi pe awọn janduku ti sọ ina si ile to le ni igba, ti wọn si jo ọkọ ayọkẹlẹ to le ni ogun ni ilu Ibadan, ni ipinlẹ Oyo.
Agbegbe Odo-Osun/Ita Baale/Aderogba ni ilu Ibadan ni iroyin naa sọ wi pe iṣẹlẹ naa ti waye.
Amọ, ileeṣẹ ọlọpaa ti fi lede wi pe ko si ohun to jọ bẹẹ to waye, ati wi pe awọn oniroyin ẹlẹjẹ lo gbe iroyin naa.
Ninu atẹjade ti alukoro ọlọpaa nipinlẹ Oyo, Olugbenga Fadeyi fi lede lo ti sọ wi pe ọwọ awọn tẹ janduku mẹfa to ṣọṣẹ ni agbegbe Labiran ni Ọgbọnjọ, Osu Kini, ọdun 2021.
Fadeyi ni ohun to ṣẹlẹ ni pe awọn janduku to wa ni agbegbe naa jade sita ni Ọjọ Kọkandinlọgbọn, Oṣu Kinni, ọdun 2021 lati ṣekọlu si awọn ile itaja to wa ni agbegbe naa, ti wọn si dana si oju kan nibi ti wọn pagọ si.
O ni ile kan ati ileesẹ itaja ni wọn kọlu, ti eyi si jasi ipe gbajawiri ti wọn pe awọn ọlọpaa lati pese alaafia si agbegbe naa.
Awọn janduku naa jade ni agbegbe Aderogba ni asalẹ ti wọn si kọlu agbegbe Bayerunka ati Ogbori Efon ni ilu Ibadan.
''Awọn ọlọpaa ati ikọ Amọtẹkun ni wọn ran lọ si agbegbe naa, ki wọn to ri awọn kan mu, ti wọn si pa ina ti wọn da si agbegbe naa.''
- Wo bí o ṣe lè di ọmọ onílùú ní Dubai pẹ̀lú òfin tuntun orílẹ́èdè U.A.E.
- Òfin kónílé-ó-gbélé gbòde nílùú Igangan lórí ẹ̀rù pé Fulani le k'ógun wá lẹ́yìn àbẹ̀wò Igboho
- Èèyàn mẹ́tàdínlógún(17) jọ́ná ráúráú nínú ìjàmbá ọkọ̀ bọ́ọ̀sì lópòpóónà Bode-Saadu sí Jebba
- Ènìyàn 1,883 míì tún ti lùgbàdì ààrùn Covid-19 ní Nàijíríà
- Seyi Makinde, Akeredolu, òfo ni kùrù-kẹrẹ yín lọ́dọ̀ Buhari lórí ìpèsè ààbò - Falana
Eleyii mu ki awọn janduku naa sa kuro ni agbegbe naa, ti alaafia si ti jọba.
Alukoro ọlọpaa naa fikun pe awọn ti bẹrẹ si ti tọpasẹ awọn janduku to ku, ki awọn le fi panpẹ ọba mu wọn, ki wọn si gbe wọn lọ si ileẹjọ.
Àwọn jàndùkú kọlù àgọ ọlọ́pàá n'Ibadan, èèyàn méjì kú
Iroyin to tẹ wa lọwọ lati ilu Ibadan sọ pe, awọn afurasi janduku kan ti ṣe ikọlu sawọn ọlọpaa nitori bi wọn se mu awọn afurasi meji ti wọn lo n da omi alaafia ilu ru.
A gbọ pe ikọlu naa bẹrẹ lagbegbe Odo-Osun lọjọbọ, ti o si tan de agọ ọlọpaa to wa ni Mapo.
Eeyan meji ku ninu iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ti wi.
- Ó wù mí kí ń padà sí Igangan, tí wọn bá fún mi láàyè - Seriki Fulani
- Èèyàn 75 di àwátì, 18 jáde láyé bí agbébọn ṣe gbàjọba yíka Nàíjíríà l‘Ọ́jọ́bọ
- Bí Sunday Igboho bá tàpá sófin, kí lẹ ṣe fáwọn ọ̀daràn Fulani tó ń pa èèyàn - Gani Adams
- 'Bí a ṣe rí ibi ti ọ̀gágun olórí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó ti kú kówó pamọ́ sí.'
- Ewu ń bẹ pẹ̀lú kíkó Amotekun lọ Ibarapa lórí ọ̀rọ̀ Fulani - Baajigan Ilaji Ile
- Sunday Igboho ṣọ́ra ṣe, jẹ́ kí Seyi Makinde ṣiṣẹ́ tí òfin gbé le lọ́wọ́ - Ooni Ife
- Ẹlẹ́nu méjì ni ìjọba Buhari, òun ló ń pín Nàíjíríà yẹ́lẹyẹ̀lẹ - Wole Soyinka
- Wo ìgbẹ̀yìn àwọn ọlọ̀tẹ̀ Yorùbá tó ran Fulani lọ́wọ́ láti kógun ja ìlú Osogbo
Lọjọbọ ni awọn ọlọpaa mu awọn janduku meji kan ladugbo Odo-Osun nitosi Mapo.
Bi awọn akẹgbẹ wọn ṣe ri pe ọwọ ti tẹ wọn, ni wọn gbiyanju lati fipa tu wọn silẹ lọwọ awọn ọlọpaa.
Amọ ṣa, ọlọpaa ṣina bolẹ fun wọn ni agbegbe Odo-Osun ti eeyan kan si ku nibẹ.
Lẹyin ikọlu ti Odo-Osun yii, awọn janduku taa n wi yi tun ṣigun lọ si agọ ọlọpaa to wa ni Mapo, lati fẹhonu han lori eeyan wọn kan ti o ku.
Ninu wọdu-wọdu to waye nibẹ, awọn ọlọpaa tun yinbọn lati daabo bo agọ wọn, eeyan kan tun fara gbọta to si gba ibẹ ku.
Alukoro ọlọpaa ni ipinlẹ Oyo, Olugbenga Fadeyi fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fawọn akọroyin ninu atẹjade kan to fi sita.
O ni ''lẹyin tawọn ọlọpaa mu awọn janduku meji kan, arakunrin kan ti wọn n pe orukọ rẹ ni ''Packaging'' lewaju awọn janduku mii to to ọgbọn,
lati ṣigun bo agọ ọlọpaa, ki wọn le tu akẹẹgbẹ wọn silẹ''