You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
EndSARS: Ìgbé "a kò fẹ́ SARS mọ́" lára ìlú gbé lọ bá Akarigbo ìlú Remo
Ikọlu ti waye laarin awọn ileeṣẹ ọlọpaa nilu Sagamu ati awọn ara ilu to n ṣe iwọde ifẹhonu han nitori agbabọọlu ti wn ni oṣiṣẹ SARS kan pa.
Kaakiri oju opo Twitter ni aworan ati fọnranfidio to ṣe afihan bi awọn oluwọde ti ṣe n ṣe ikọlu pẹlu ọlọpaa.
Ninu ọrọ tawọn eeyan fi sita loju opo Twitter naa lati ri i ka pe eeyan mẹta lara awọn oluwọde ni o ti f'ara gb'ọta.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ogun fidi ọrọ mulẹ pe lootọ lawọn kan n ṣe iwọde lori iku agbabọọlu ti oṣiṣẹ SARS kan ṣeku pa.
Alukoro ọlọpaa, Abimbola Oyeyemi ni oun ko ni iroyin nipa pe ọlọpaa yinbọn pa ẹnikankan ṣugbọn oun mọ pe iwọde n waye ni Sagamu.
Abimbola ni iroyin tẹ oun lọwọ pe awọn eeyan kan fẹ lọ kogun ba awọn ọga ọlọpaa to wa ni agọ ọlọpaa Sagamu lati dana sun ibẹ.
''Kọmisana ọlọpaa ati awọn ọga wa miiran wa nibẹ. Wọn lọ si Sagamu lati lọ ba mọlẹbi ẹni to ku ati Akarigbo ilu Rẹmọ kẹdun iku Tiamiyu''
''Mi o mọ idi tawọn kan yoo fi wa bọ sita lati ni awọn fẹ dana sun agọ ọlọpaa''
Aworan ati Fọnran fidio ṣe afihan ikọlu
Lọwọlọwọ bayi, orukọ Sagamu lo le tente loju opo Twitter gẹ́gẹ́ bi eleyi tawọn eeyan n ran lẹnu.
Ninu awọn aworan ati fidio taa ri, awọn ara ilu lọkunrin ati lobinrin n kọrin pe awọn ko fẹ SARS nilu mọ.
Koda wọn gbe iwọde wọn de iwaju ile Akarigbo ilu Remọ pẹlu.
Yatọ si fidio yii, awọn aworan ati fidio mii ti a ko le fidi rẹ mulẹ ṣe afihan awọn eeyan to n gbe arakunrin kan wọ ile iwosan lọ ti wọn si ni awọn ọlọpaa lo yinbọn pa a.