You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Nigeria border closure: Ìdí tí Ààrẹ Buhari kò ṣe tíì ṣí ibodè tó tì pa rèé
Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ pe oun n duro de esi igbimọ to n ri si ọrọ ibode to di titi pa, eyi ni "Tripartite Committee" ko to gbe igbeṣẹ to kan lori ibode ọhun.
Buhari lo sọ orọ yii nibi ipade kan to ṣe pẹlu aarẹ orilẹ-ede Burkina Faso, Roch Marc Christian Kabore, to si ṣeleri pe atunṣe yoo waye lori ọrọ ibode naa to di titi pa laipẹ.
O ni oun ṣe tan lati ṣe ohun to yẹ lai fi akoko ṣofo ni kete ti igbimọ naa ba ti fi esi wọn ranṣe.
- Elédùmarè ló rán mi sí gbogbo Ọba Yorùbá - Oluwo
- Ọjọ́ burúkú, èṣù gbomi mu ní Ṣagamu nígbà tí agbábọ́ọ́lù kan dèrò ọ̀run
- Ẹ̀ṣẹ́ ju ẹ̀ṣẹ́ lọ! Tyson Fury d'ẹ̀ṣẹ́ bo Deontay Wilder lórí, ó gbadé WBC mọ́ ọ lọ́wọ́
- Otedola Bridge: Àwọn ẹ̀ṣọ́ ojú pópó ti gbé Ọkọ̀ agbépo tó dànù kúrò lọ̀ná
- ₦400 péré ni àfẹ́sọ́nà mi nílò, ìfẹ́ obìnrin yìí sì ló sọ mi di adigunjalè - Iṣọla Oyenusi
Awọn to wa ninu igbiimọ naa ni; ijọba Naijiria, ijọba Benin ati ijọba Niger Republic.
Buhari sọ pe "ootọ ni pe orilẹ-ede Naijira mọ erongba awọn orilẹede to yi wa ka ati ajọ ECOWAS lori ibode ti a gbe agadagodo si, ṣugbọn a o wa ojutu si ọrọ naa laipẹ."
O ṣalaye pe idi kan gboogi ti awọn ibode ọhun ṣe di titi pa ni eto aabo to mẹhẹ, paapaa julọ nitori bi awọn kan ṣe n ko ohun ija ogun ati egboogi oloro wọ orilẹede yii.
- Boko Haram tún ṣọṣẹ́ ní Adamawa, ọ̀pọ̀ òkú ṣùn, àìmọye dúkìá jóná
- Oluwo kò gbọdọ̀ kọrin òwe tàbí bá àkọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, kó má baà ba ẹjọ́ ara rẹ̀ jẹ́ - Ọ̀ràngún ṣàlàyé
- Lampard àtàwọn agbábọ́ọ̀lù Chelsea dọ́wọ́jọ di ẹrù wíwo lé Mourinho àti Tottenham lórí
- Ààrẹ Gnassingbe díje fún sáà kẹ́rin, òun àti bàbá rẹ̀ ti ṣèjọba Togo fún àádọ́ta ọdún lé mẹ́ta
Lẹyin naa ni aarẹ Buhari wa parọwa si awọn orilẹede ti ọrọ naa kan lati ni suuru.
Ẹwẹ, alaga igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Sẹnatọ Walid Jibrin ti sọ pe ibukun nla ni igbesẹ ijọba Buhari lati gbe agadagodo sẹnu ibode Naijiria.
Jibri sọ ọrọ naa gẹgẹ bi alatilẹyin ẹgbẹ awọn oniṣowo aṣọ ni Naijiiria, lẹyin to ti ṣe iṣẹ gẹgẹ bi oniṣowo aṣọ fun ọdun marundinlaadọta.
O ṣalaye pe bi ijọba ṣe ti awọn ibode naa ti ṣe adikun si bi awọn kọlọransi kan ṣe n ko aṣọ wọle si Naijiria lọna ti ko ba ofin mu.
Jibri sọ pe igbesẹ lati ti ibode naa jẹ ọkan gboogi lara aṣeyọri aarẹ Buhari lati ri pe awọn ileeṣẹ to n ṣe aṣọ lorilẹ-ede yii gbera sọ.