Bank robbery: Àwọn ọlọ́pàá ti bẹ́ síta láti ṣàwárí àwọn olè 30 tó jówó kó ní Union Bank l'Ondo

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo ti sọ pe awọn akọṣẹ mọṣẹ ọlọpaa ti bẹ sita lati ṣe awari awọn adigunjale ti wọn yabo ile ifowopamọ Union Bank to wa niluu Ode-Irele nipinlẹ Ondo.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa l'Ondo, Tee Leo-Ikoro to fidi ọrọ naa mulẹ ṣalaye pe adigunjale naa to ọgbọn niye.

Ni deedee ago mẹrin irọlẹ ni awọn adigunjale naa rọna wọle si ile ifowopamọ Union Bank naa.

Leo-Ikoro sọ pe agọ ọlọpaa to wa niluu naa lawọn ọdaran naa kọkọ kọlu ki wọn to morile ile ifowopamọ nibi ti wọn ti ji obiti biti owo lọ.

Bakan naa, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa fidi rẹ mulẹ pe awọn adigunle jale naa ji ọpọ ibọn ko lọ ni agọ ọlọpaa.

O ni ado oloro lawọn ọdaran ọhun lo lati fọ ibi tawọn ọlọpaa n ko ibọn pamọ si.

Amọ, Leo-Ikoro sọ pe ko si ẹni to ba iṣẹlẹ ọhun bo tilẹ jẹ wọn yinbọn fun awọn eeyan kan.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe awọn adigunjale naa ko ni lọ lai foju wina ofin.