You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ondo Election 2020: Agboola Ajayi ní ₦12m lòun ń gbà lóṣù, kìí ṣe ₦13m
Igbakeji gomina nipinlẹ Ondo, Agboola Ajayi ti fesi pada fun gomina Rotimi Akeredolu, to ni oun n gba miliọnu mẹtala naira losu.
Ajayi, tii se oludije gomina fẹgbẹ oselu ZLP lọwọ lọwọ bayii wa salaye pe, miliọnu lọna ọtalelẹẹdẹgbẹrin o din mẹwa naira, 750m ni gomina Akeredolu n gba losoosu fun owo ipese aabo taa mọ si Security Vote.
Ko tan sibẹ o, Ajayi tun fikun pe miliọnu lọna aadọjọ naira, 150m, ni Akeredolu tun n gba lowo osu, to si n fun oun ni miliọnu mejila naira ninu rẹ losu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sunday Igboho kàn ń gbé ‘Camera’ lẹ́yìn kiri, kí wọ̀n lè rò pé ó ń jà fún Yorùbá - Gani Adams
- INEC kéde agbègbè ẹsẹ̀ odò 270 ti èrú ìbò ti le wáyé ní ìpínlẹ̀ Ondo
- Ẹgbẹ́ tó ń fẹ́ Oduduwa Republic kọ̀wé ẹ̀hónú sí UN, EU, AU àti ìjọba Gẹ̀ẹ́sì
- Àjọ EFCC ti mú ọ̀dọ́kùnrin mẹ́wàá lórí ẹ̀sùn jìbìtì lílù lórí ayélujára ní Oyo
- Kíni ó lè mú kí ọmọbìnrin sá kúrò nílé láti ìpínlẹ̀ Plateau lọ sí Ekiti?
- Ọkọ̀ ọ̀fẹ́ ní ọmọ tuntun jòjòlò tí wọ́n bí sínú ọkọ̀ òfurufú yóò máa wọ̀ títí ayé rẹ̀- Egypt Air
- Ẹ lọ ṣí gbogbo ilé ẹ̀kọ́ padà ní Nàíjíríà - Ìjọba àpàpọ̀
- Irọ́ ni o! Ìyàwó Ọ̀ọ̀ni Ogunwusi kò bímọ tuntun
- A kò ṣetán láti fa olùdíje kanṣoṣo kalẹ̀ fún ìbò gómìnà l‘Ondo - Àgbáríjọ ẹgbẹ́ òṣèlú
Igbakeji gomina ipinlẹ Ondo sisọ loju ọrọ yii ninu atẹjade kan ti akọwe iroyin rẹ, Allen Sowore fisita pẹlu afikun pe, ẹnu ya oun pe Akeredolu n pariwo pe oun n fun Ajayi ni miliọnu mẹtala naira losu, bii ẹni pe ẹbun lo n fun-un.
O ni gomina Akeredolu ko fun oun ju miliọnu mejila naira lọ losu, ti ko tiẹ wa fun oun mọ bayii.
Ajayi salaye pe awọn owo naa lo wa fun owo itọju ọọfisi oun, owo ajẹmọnu awọn osisẹ to wa lọdọ oun, owo epo mọto ati itọju awọn ẹsọ oun.
"Owo yii le pọ lootọ amọ ko to fun iye eeyan to tọ si ati awọn eeyan ta fi gbọ bukata wọn."
Bakan naa lo tun sisọ loju rẹ pe, iyawo ati ọmọ Akeredolu n gba ọpọ miliọnu naira bii owo ajẹmọnu losoosu lai si ni ipo kankan ti ofin la kalẹ.
₦13m ni Agboola Ajayi ń gbà lóṣù àmọ́ kò ní ìtẹ́lọ́rùn: Akeredolu
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe, Gomina Ipinlẹ Ondo ati oludije lẹgbẹ oṣelu APC, Oluwarotimi Akeredolu ti ni ohun gbogbo ni oun fi tẹ Igbakeji gomina ni ipinlẹ Ondo, Agboola Ajayi lọrun, amọ o ya abara mu oore jẹ.
Gomina Akeredolu sọ eleyii lasiko to n ba awọn eniyan sọrọ lori ẹrọ amohunmaworan ni ipinlẹ Ondo.
Akeredolu ni Agboola Ajayi ko fẹ duro di igba tirẹ, o fẹ fi waduwadu gba ipo gomina, eleyii ti ko le ṣeeṣe.
- Ọ̀pọ̀ aráàlú Owo wà nílé ìwòsàn, síbẹ̀ APC àti PDP kò gba ẹ̀bi
- Ẹ fura, làásìgbò le wáyé ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́fà yìí lásìkò ìbò gómìnà Ondo - YIAGA
- Ẹ gbọ́ òhun tí àwọn olùdíjé sípò gómìnà nípínlẹ̀ Ondo sọ nípa Bàbá ìsàlẹ̀...
- Wike, má gbé jàgídíjàgan wá sí Ondo, APC kò ní ṣ'èèrú nínú ìdìbò gómìnà tó ń bọ̀- Kalejaye
- Èyí lohun tó fa ìjà àwọn tọ́ọ̀gì APC, PDP l'Ondo
"Mo ma n ran Agboola lati soju mi ni awọn ibi to ṣe pataki, amọ ko ni itẹlọrun.
Awọn eniyan ti kilọ fun mi lati maṣe gbe ọkan le Agboola, amọ mi o gbọ titi to fi bẹrẹ si ni ṣe alatako mi.
Ko si igbakeji gomina to n gba owo oṣu ti Agboola n gba ninu itan ipinlẹ Ondo, ẹgbẹrun mẹtala miliọnu naira lo n gba ni owo oṣu .
Gbogbo nnkan ni mo fi tẹ lọrun, amọ o ṣi fi ọbẹ ẹyin jẹ mi ni isu."
Amọ, gomina Akeredolu fikun wi pe, gbogbo awọn alatako oun ni oun ṣetan lati dariji gẹgẹ bi ọmọ lẹyin Kristi ti oun jẹ, ko le e mu ki oun ni ikunsinu si ẹnikẹni.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sunday Igboho kàn ń gbé ‘Camera’ lẹ́yìn kiri, kí wọ̀n lè rò pé ó ń jà fún Yorùbá - Gani Adams
- Ẹ lọ ṣí gbogbo ilé ẹ̀kọ́ padà ní Nàíjíríà - Ìjọba àpàpọ̀
- Irọ́ ni o! Ìyàwó Ọ̀ọ̀ni Ogunwusi kò bímọ tuntun
- A kò ṣetán láti fa olùdíje kanṣoṣo kalẹ̀ fún ìbò gómìnà l‘Ondo - Àgbáríjọ ẹgbẹ́ òṣèlú
- Donald Trump àti ìyàwó rẹ́ ti lùgbàdì àrùn CoronaVirus
- Fídíò rèé lórí bí Sunday Igboho ṣe korò ojú sí ìwà ọ̀dàlẹ̀ nílẹ̀ Yorùbá
- Ìfẹ́ Yorùbá ló mú mi fi ẹ̀mí wéwu láti kojú ajínigbé ní Kishi - Sunday Igboho
Gomina naa ni o da oun loju wi pe, oun yoo jawe olubori ninu eto idibo sipo gomina to n bọ, nitori awọn ti ṣiṣẹ ribiribi ni ipinlẹ Ondo.
"Gbogbo iṣẹ akanṣe ti ijọba Mimiko ṣe pati, ni a ti pari patapata, ti a si tun kọ ẹẹdẹgbẹta ileewe alakọbẹrẹ ni ipinlẹ naa, eleyii to ti mu ilọsiwaju ba eto ẹkọ ni ipinlẹ Ondo.
- Buhari, ayẹyẹ kí là ń ṣe gan, ṣé ti ìpànìyàn àbí ìjínigbé? - Aráàlú ń bèèrè
- Ẹ fura, làásìgbò le wáyé ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́fà yìí lásìkò ìbò gómìnà Ondo - YIAGA
- Wo ìṣẹ̀lẹ̀ márùn-ún tí kò bá pín Nàíjíríà sí yẹ́lẹ-yẹ̀lẹ
- Bọ́ síta láti ṣe ìwọ́de mọ́ ìjọba Nàìjíríà lónìí, ko rugi oyin - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
- Ẹ̀yin ọlọ́pàá 10,000 tí ọ̀gá ọlọ́pàá gbà ṣíṣẹ́ ní 2019, ẹ padà sílé - Iléẹjọ́ pàṣẹ
A tun ti gba owo lati tun adagun omi Owena ṣe ati awọn marun un miran, eleyii ti yoo mu ilọsiwaju ba ipese omi ni ipinlẹ Ondo."