Ondo election 2020: Kalejaye ní APC kò ní ṣ'èèrú nínú ìbò gómìnà tó ń bọ̀, Wike má gbé jàgídíjàgan wá

Ẹgbẹ oṣelu APC ti kilọ fun Gomina ipinlẹ Rivers Nyesom Wike ko jawọ lapọn ti ko yọ nitori APC ko ni erongba lati yi ibo ninu ibo gomina ipinlẹ Ondo ti yoo waye lọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun 2020 yii.

Ṣaaju ni Gomina Wkie to jẹ eekan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP sọ lori ẹrọ amohunmaworan wi pe ẹgbẹ oṣelu APC ti ṣeto lati yi ibo gomina to n bọ l'Ondo.

Amọ, ninu atẹjade kan ti alukoro ẹgbẹ oṣelu APC ẹka ti Ondo, Alex Kalejaye fi sita lọjọ Ẹti, APC sọ pe kaka ki awọn yi ibo, ohun ti awọn yoo sọ fun araalu ni pe ki wọn dibo fun Gomina Rotimi Akeredolu lẹẹkan si i lẹyin iṣẹ ribiribi to ti ṣe laarin ọdun mẹrin akọkọ.

Ọgbẹni Kalejaye sọ ninu atẹjade ọhun pe Wike ko mọ bi eto idibo ṣe maa n lọ ni irọwọ-rọsẹ lo jẹ ko sọ pe idibo gomina ipinlẹ Edo to waye laipẹ yii lo lọ ni irọwọ rọsẹ julọ.

O ni ẹgbẹ APC ko nilo lati ṣe eeru ninu ibo ni ipinlẹ tawọn araalu ti gba ẹgbẹ naa tọwọ teṣẹ lọdun mẹrin sẹyin.

''O da wa loju ninu ẹgbẹ oṣelu APC pe Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu, SAN ati oludije fun igbakeji Gomina pẹlu rẹ, Lucky Ayedatiwa to gbangba sun lọyẹ ninu eto idibo to n bọ papaa julọ pẹlu awọn iṣẹ akansẹ ti ijọba Akeredolu ti ṣe laarin ọdun mẹrin akọkọ nipinlẹ Ondo,'' Ọgbẹni Kalejaye lo sọ bẹẹ.

O tun kilọ fun Gomina Wike ninu atẹjade naa pe ki o maa gbe oṣelu bo ba a o pa a, boo ba o bu lẹsẹ wa si ibi idibo gomina ipinlẹ Ondo.

APC ni eto idibo lawọn fẹ ṣe kii ṣe ogun lawọn n gbaradi fun un.