Ondo Election 2020:Lóòtọ́ làwọn tọ́ọ̀gì APC kọlu PDP ní Oba Akoko, ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ - Ọ̀lọ́pàá

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo ti ṣalaye pe lootọ lawọn janduku lẹyin ẹgbẹ oṣelu APC atawọn ti PDP kọlu ara wọn ni Ọjọru ni ilu Ọba Akoko ṣugbọn iwadii ti bẹrẹ lati mọ ohun pato to fa wahala naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo, DSP Tee Leo-Ikoro ṣalaye fun BBC pe iṣẹlẹ naa ko dun mọ kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo to bẹẹ gẹ to fi pe awọn eekan ẹgbẹ oṣelu gbogbo ni ipinlẹ naa fun ijiroro lori rẹ l'Ọjọbọ.

O ni wahala to bẹ silẹ naa tako adehun to wa laarin awọn ẹgbẹ oṣelu mejeeji ati ọlọpaa pe ko gbọdọ si ẹgbẹ oṣelu meji to gbọdọ maa ṣe ipolongo lagbegbe kan naa lasiko kan naa.

O ṣalaye pe awọn ẹgbẹ oṣelu PDP lo n ṣe ipolongo ibo wọn ni ilu Ọba Akoko nigba ti ẹgbẹ oṣelu APC n kọja laarin ilu naa lọ si ilu Ikare Akoko. Nibẹ ni wọn ti kọlu ara wọn.

Ileeṣẹ ọlọpaa ti pe ipade lori iṣẹlẹ naa pẹlu ileri pe irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ ko ni ṣẹyọ mọ ṣsaju ati lasiko idibo gomina ni ipinlẹ Ondo to n bọ lọna.

Ọpọ̀ ọkọ̀ bàjẹ́ nígbà tí alátìlẹ́yìn PDP àti APC kọlù àrà wọ́n l'Ondo

Awọn alatilẹyin Gomina Rotimi Akeredolu ipinlẹ Ondo ati akẹgbẹ rẹ ninu ẹgbẹ PDP Eyitayo Jegede ti n naka abuku sirawọn lori ẹni to jẹbi ikọlu to waye lọjọru.

Ikọlu naa gẹgẹ bi ohun ta ri gbọ waye nigba tawọn ikọ ipolongo mejeeji pade ni ilu Oba Akoko ni ijọba ibilẹ Akoko West.

Lẹyin ti gbogbo nkan walẹ tan, ọpọ ọkọ ni wọn bajẹ ti awọn ẹgbẹ mejeeji si n naka si ara wọn pe ẹnikeji lo kọkọ da wahala silẹ.

Ninu ọrọ ti Eyitayo Jeged sọ fun BBC Yoruba, o ni awọn ti gba iyọnada ṣaaju lọdọ ọlọpaa ki awọn to bẹrẹ ipolongo.

''Iyalẹnu lo jẹ fun wa lati ri ki awọn ọmọ ẹgbẹ APC ya de niwaju aafin Oba Akoko ti wọn si bẹrẹ si ni ṣe ikọlu awọn eeyan wa''

Eyitayo sọ pe oun wa ni ọdọ Kọmisana ọlọpaa lati lọ fi ẹjọ suin nitori pe awọn janduku ẹgbẹ APC ba ọkọ awọn to to ogun jẹ ninu ikọlu naa.

O ṣalaye pe oun ti pe Gomina Akeredolu lori ago ti o si ni pe oun ti kọja tan ki iṣẹlẹ naa to waye ati pe oun ko mọ pe iru nkan bẹ waye.

BBC kan si alaga ẹgbẹ APC ni Ondo lati gbọ alaye lẹnu rẹ.

Alagba Ade Adetimehin sọ pe oun gẹgẹ bi ẹnikan ko mọ igba ti ikọlu naa waye nitori ọkọ ti oun wa ninu rẹ kọja ni Oba Akoko ti wọn ko si kọlu ẹnikankan

''Nigba ti a kọja lọ, a ri pe awọn PDP naa wa nilu Oba Akoko. Lẹyin igba ti a ti kọja ti Gomina ti kọja a ko ri ẹyin la ti mọ boya awọn eeyan kan ti da awọn eeyan wa lẹyin''

O fi kun pe ''a o ni igbagbọ pe PDP yoo 'se ipolongo wọn loni. A ti gba aaye lati ṣe ipolongo. Nigba ti a de ilu Ikare la gbọ pe wọn ṣe ikọlu si ọkọ wa.''

BBC Yoruba gbiyanju lati ba alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ondo arakunrin Tee-Leo Ikoro sọrọ lori iṣẹlẹ yi ṣugbọn ko gbe ago rẹ.

Jàńdùkú olóṣèlú gbàkóso ilé aṣòfin l'Ondo

Awọn janduku oloselu ti gba akoso ile asofin nipinlẹ Ondo, ti wọn si n da idarudapọ silẹ nibẹ

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni o le ni ọgọfa awọn tọọgi naa ti wọn gbarodan siwaju ile asofin ọhun, pẹlu ogunlọgọ ọkọ ayọkẹlẹ wọn.

Bẹẹ ba gbagbe, a ti n mu iroyin wa fun yin tẹlẹ pe nnkan ko fararọ nile asofin ipinlẹ Ondo nitori eto idibo gomina to sunmọ etile.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Laipẹ yii si ni ile asofin naa gbindanwo lati yọ igbakeji gomina, ti omi alaafia ibẹ ko si toro nitori awọn asofin mẹsan to tako igbesẹ naa.

Bi gbogbo ọrọ naa ba se jẹ, BBC Yoruba wa ni sẹpẹ lati mu ẹkunrẹrẹ iroyin wa fun yin.