Egypt Air: Inú wa dùn pé Hiyam Nasr Daaban tó jẹ́ Ìyá àti ọmọ wà ní àlááfíà

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ọkọ̀ ọ̀fẹ́ ní ọmọ tuntun jòjòlò tí wọ́n bí sínú ọkọ̀ òfurufú yóò máa wọ̀ títí ayé rẹ̀- Egypt Air

Arabinrin Hiyam Nasr Daaban lo dede bẹrẹ si ni rọọbi ninu ọkọ ofurufu Egypt Air , eleyii to mu ki awakọ ofurufu naa tiraka lati ba silẹ ni pajawiri.

Ọpẹlọpẹ dokita to wa ni ọkọ baalu naa lo gbẹbi arabinrin naa, ti o si bi ọmọ naa ni ayọ ati alaafia.

Awọn alasẹ Egypt Air fi idunnu wọn han pupọ.

Egypt Air ni: Inu wa dun pe iya ati ọmọ wa ni alaafia

Ileeṣẹ ọkọ ofurufu, Egypt Air loju opo ikansiraẹni Twitter wọn ni wọn ti fi iroyin naa lede.

Wọn fi lede wi pe awọn ti fun ọmọ naa ni aṣẹ lati ma wọ ọkọ ofurufu wọn lọfẹ ni gbogbo aye rẹ.

'Ọmọbinrin tuntun jojolo naa ni wọn bi ninu ọkọ ofurufu, ti o si gba tikẹẹti ọfẹ titi aye rẹ lati wọ ọkọ baalu '

Ọkọ ofurufu naa n lọ lati orilẹede Egypt lo si London ni ki iṣẹlẹ naa to waye, ti wọn si tiraka lati lọ si Munich, ni Germany, amọ ọmọ naa wa ki o to di wi pe wọn de ibẹ.

Bakan naa ni ileeṣẹ Egypt Air naa ba iya ati mọlẹbi ọmọ tuntun naa yọ fun ọre ọfẹ ti wọn ri gba lati bi ọmọ naa ni ayọ ati alaafia.