Nigeira at 60 independent celebration: Sanwo-Olu gbàlejò àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ̣ọgọ́ta, El-Rufai dá ẹlẹ́wọ̀n 25 sílẹ̀

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti gbalejo akẹkọọ ọgọta lati ileewe alakọbẹrẹ ni ipinlẹ Eko lati ṣe ayajọ ọjọ ominira orilẹ-ede Naijiria.

Ninu atẹjade ti akọwe eto iroyin fun gomina Sanwo-Olu, Gboyega Akosilekọ jade, ni wọn ti fi lede pe igbalejo naa waye ni Ile Ijọba ni Marina, lagbegbe Tafewa Balewa Square (TBS) ni ilu Eko.

Gomina sanwo-olu wa gba awọn akẹkọọ ni imọran lati mase ro orilẹede Naijiria pin, nitori yoo dara fun wọn.

O fikun un wi pe gomina Eko, lo ayẹyẹ naa lati fi ṣe idanilẹkọ fun awọn ọmọde naa lori bi wọn ṣe le mu iwuri ba orilẹede Naijiria ati awọn ohun to yẹ ki wọn ṣe gẹgẹ bi ọmọ orilẹede Niajiria rere.

Bakan naa ni Gomina Sanwo-Olu rọ awọn ọmọ naa lati ma hu iwa rere ti yoo mu idagbasoke ati iṣọkan gbooro si ni Naijiria.

Ni ipinlẹ Kaduna, Gomina Nasir El- Rufai da awọn ẹlẹwọn marundinlọgbọn silẹ lati ṣe ayẹyẹ ayajọ ọjọ ominira orilẹede Naijiria.

Gomina El-Rufai ni ọjọ aanu ni Ọjọ ominira Naijiria, nitori naa ni awọn ṣe ṣaanu fun awọn ẹlẹwọn ti wọn wa ni ọgba ẹwọn ni Kaduna.

O ni bi awọn ṣe yọnda awọn kan lati ma a lọ sile layọ ati alaafia ni awọn din iye ọjọ ti awọn miran fe lo ni ọgba ẹwọn ku.

Gomina ipinlẹ Kaduna fikun un pe alaafia jẹ ijọba oun logun lọna ati mu idagbasoke ba ipinlẹ Kaduna ni asiko ijọba awọn oun ati ni ọjọ iwaju.