Coronavirus:: Òògùn ìtura dé fún Covid-19! Ọ̀dọ̀ fásitì jànkàn Oxford ló ti jáde

Oogun arun Coronvirus kan ti wọn fiaridaju han pe o n ṣiṣẹ ti jade lati ile iwe giga fasiti Oxford eyi to si fi han pe ko mu ewu dani rara.

Bakan naa wọn jẹ ko di mimọ pe o maa n tọ agọ ara sọna nipa ohun to yẹ ko ṣe ki ara lee ji pepe.

Ayẹwo rẹ ti wọn ṣe lara eeyan ẹgbẹrun kan o le mẹtadinlọgọrin fi han pe abẹrẹ naa gbe awọn ajagun inu ara dide toloyinbo n pe ni 'antibodies' ati eroja ara mii fun ijagun (white blood cell) eyi to lee doju ija kọ arun Coronavirus.

Ohun to have iwadii yii jade ni Ireti gidi amọ ṣa, o ti ya ju lati mọ boya eyi nikan ti to lati dajọ pe o nṣiṣẹ lati da abo bo ara bẹẹ si ni awọn oogun ayẹwo mii ṣi wa lọna.

Orilẹede Amẹrika ti beere lati ra miliọnu lọna ọgọrun oogun naa bayii.