Oshiomhole Judgement: Ẹ gbọ́ ǹkan ti agbẹ́jọro sọ lórí ìdájọ ti Kano

Adams
Àkọlé àwòrán, Idájọ wo ni ẹ ro pe ó jẹ́ ojúlówó nínú ti Kano àti ti Abuja nípa Adams Oshiomhole?

Lóri awuyewiye ìyọnípò alága ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive, Congress APC Adams Oshiomole ni ilé ẹjọ gíga nílu Abuja ní ọjọru

Ìrọ̀lẹ́ ọjọbọ ni ìròyìn tún kan pé, ilé ẹjọ gíga míràn ní ìpínlẹ̀ Kano, tún ni ko ṣeeṣe, a fi ki Oshiomhole pada sáàye rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC.

Idàrúdapọ ní ọ̀rọ̀ náà wá dá silẹ̀ ti ọ̀pọ̀ si n bere pe irú ìgbésẹ̀ wò ni ọlọpaàá yóò gbé àti pe kíní Oshiomhole gan yóò ṣe, nígba ti ilé ẹjọ méjì ti wọ́n wà ni ipò kan náà n pasẹ ọtọọtọ.

Láti wá ojúútu si ọ̀rọ̀ sunukùn yìí ní BBC Yoruba ṣe képe àmofin ti o fi oju sunukùn wó laáti sàlàye igbésẹ̀ rẹ̀ fún gbogbo àwọn tọ́rọ̀kan

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, agbẹjọrò Dayo Akinlaja (SAN) ní ǹkan ti o tini lójú to si bani nínú jẹ́ gbáà ni ọ̀rọ̀ náà bi ilé ẹjọ to jọ ni agbára bákan náà jọ ń dá ẹjọ ọtọọtọ.

''Nkan tí iwé òfin sọ nípa ilé ẹjọ to ni agbára kan náà, ikan ko ni àṣẹ kankan to le pa fún ikèjí, nínú ọ̀rọ̀ ti a si n gbọ lọ́wọ́, ko yẹ ki ipinlẹ Kano gbọ́ ẹjọ yẹn.''

O fikun ọrọ rẹ pe ''o yẹ ki adájọ fi ìyà jẹ agbẹ́jọrò ti ó gbé ẹjọ náà wa.

''Ile ẹjọ giga apapọ ko ni ẹtọ la'ti dá ẹjọ kọọtu ti Abuja nù. Adams Oshiomhole ti wọn dájọ fún lo ni ẹtọ lati lọ si kọọtu láti pe ẹni to pe lẹ́jọ ni ẹjọ.''

Bi nkan tiṣe n lọ bayi, ko si ẹni to mọ idajọ eleyi ti ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria yoo tẹle lori idajo boya ki Adams Oshiomole wa loriipo rẹ tabi ki o yẹba ṣẹgbẹ kan naa.

Wahala to de ba Adams Oshiomole jẹ eleyi to niṣe pẹlu bi awọn ọmọ ẹgbẹ APC kan ti ṣe sọ wi pe awọn ko fẹ ri imi rẹ laatan.