Harry and Meghan: Mí o ṣààdédé gbé ìgbésẹ̀ láti kúrò nílé Ọba

Ọmọọba ilẹ Gẹẹsi ti o si tun jẹ "Duke ti Sussex" ti sọ pe igbagbọ loun fi gbe igbẹsẹ lati yẹra kuro nile ọba nitori ko si nkan mii ti oun le ṣe.

Nibi apejẹ kan ti oun ati iyawo rẹ Meghan kopa nibẹ nirọlẹ ọjọ Aiku ni o ti sọ pe o wu awọn lati maa ṣiṣẹ sin yeye Ọba lai gba owo ṣugbọn ''ko le ṣeeṣe''

Eyi ni igba akọkọ ti yoo sọrọ nita gbangba lori ọrọ yii lati igba ti oun ati iyawo rẹ Meghan ti kede pe awọn fẹ yẹra kuro nile ọba.

Ọmọọba naa ni oun ri ayọ ati idunnu ti oun ti n wa pẹlu Meghan ṣugbọn oun fẹ ki o ye awọn eeyan pe awọn ko lọ lai wẹyin wo.

''Ile ni ilẹ Gẹẹsi jẹ fun mi, ko si oun ti yoo si yi i pada''

Harry sọ pe ohun to n ṣẹlẹ n ṣafihan iru bi nkan ko ṣe rọrun fun oun eleyi to mu ki oun fi mọlẹbi oun pamọ lati le gbe igbe aye alaafia.

Nibẹrẹ oṣu yii ni ọmọọba Harry ati Meghan sọ pe awọn fẹ yẹra kuro nipo gẹgẹ bi aṣaaju mọlẹbi ọlọba ilẹ Gẹẹsi tawọn si fẹ́ da duro funra awọn.

Lọjọ Abamẹta ni ikede wa lati aafin Buckingham Palace pe wọn o ni maa lo oye ọlọmọọba wọn mọ ti wọn ko si ni kopa ninu awọn iṣẹ to jọ mọ jíjẹ́ ọmọ ọba.

Wòó nínú àwòrán: ìgbé ayé Harry àti Meghan ṣáájú ìyapa kúrò nílé Ọba

Ọmọọba Harry ati aya rẹ ti a mọ si Duke ati Duchess Sussex lẹyin igbeyawo wọn ni wọn ko ni lo orukọ oye ile ọla to jẹ ile Ọba UK mọ.

Koda, wọn ko ni fọwọ kan owo ilu mọ ni ile Ọba ni Buckingham.

Bakan naa ni wọn pinnu lati da miliọnu meji ati irinwo pọun ile UK ti ile Ọba fi ba wọn tun ile Cottage ti wọn n gbe lẹyin igbeyawo wọn ṣe pada Harry àti Meghan kò ní lo orúkọ oyè wọn mọ́, wọn kò sì lẹ́tọ̀ọ́ sí owó ilú mọ́ ní UK.

Owó ara wọn ni wọn yoo maa na pẹlu ileri lati ma doju ti Ọbabinrin ninu iwa ati iṣe wọn nibikibi ti wọn ba wa.

Gbogbo aworan yii lo ni awọn to ni wọn bi a ṣe darukọ wọn.