Orthodox Christians Epiphany: Àwọn krìstíẹ́ní yìí n wẹ̀ nínú omi tútù fún àjọyọ̀ ìrìbọmi Jesu

Awọn olujọsin kaakiri Russia ati Ila oorun Yuroopu ti n 'jare ọyẹ' pẹlu bi wn ṣe n wẹ ninu odo ti omi rẹ ni yìnyín, fun ajọyọ ifihan Jesu (Epiphany).

Ọkan pataki ni lara awọn ọjọ isinmi ninu kalẹnda awọn kristiẹni igbagbọ atijọ.

Ajọyọ naa to maa n waye ni ọjọkọkandinlogun, oṣu Kinni, maa n wa fun iranti iribọmi Jesu, ninu odo Jọdaani.

Lati ṣe ajọyọ ọjọ naa, ọpọlọpọ awọn Kristiẹni igbagbọ atijọ (orthodox) maa n ri ara a wọn sinu iho omi tutu.

Wọn le ki ara wọn sinu omi lẹẹmẹta lati bu ọla fun Mẹta-lọkan.

Igbagbọ wọn ni pe aṣa naa maa n mu ilera pipe wa fun awọn olujọsin, to si tun maa n wẹ ẹṣẹ wọn danu.

Ninu aworan oke yii, alufaa ijọ igbagbọ atijọ kan n ya omi si mimọ ni Svyatoye, to wa ni ẹyin odi olu ilu orilẹ-ede Russia, Moscow.

Awọn olujọsin gbagbọ wi pe gbogbo omi maa n di mimọ ni ayajọ ifihan Jesu (Epiphany).

Awọn kan ti lẹ ro pe omi to tutu daadaa pẹlu yìnyín ni anfaani fun ilera.

Awọn olujọsin ijọ igbagbọ atijọ n bẹ sinu omi tutu oníyìnyín odo Sava nilu Belgrade.

Ninu aworan yii, obinrin kan n wọ inu omi nilu Omsk, l'orilẹ-ede Russia, nibi ti otutu ti n gba yayaaya lasiko yii.

Awọn to n ṣọ ẹlẹwọn n wo bi ẹlẹwọn kan ṣe n ri ara rẹ bọ omi ni ọgba ẹwọn alagbara kan to wa ni Omsk.

Awọn olujọsin korajọpọ lati ya aworan lẹyin ti wọn ti luwẹ tan ninu odo Sava, to wa ni ilu Belgrade.

Gbogbo aworan ti a lo lo ni orisun to ti wa.