PDP Kogi Primary: PDP yóò yan olùdíje tí yóò gbé àsíá ẹgbẹ́ fún ipò gómìnà

Eniyan meje ninu awọn mẹrindinlogun to n dije dupo ninu idibo abẹle ẹgbẹ oselu PDP, saaju idibo sipo gomina ni ipinlẹ Kogi, ti fi ipo silẹ.

Ninu atẹjade ti wọn fi lede, ọkan ninu awọn agbẹnusọ fun ẹgbẹ oselu PDP, Gabriel Aduku sọ wi pe, awọn mẹjo naa fi ipo silẹ fun Gomina ipinlẹ naa tẹlẹri, Idris Wada to n dije dupo ninu idibo abẹle naa.

Aduku ni awọn oludije naa gbe igbesẹ ọhun lẹyin ti wọn se ipade apero nibi ti wọn ti gba awọn eniyan ni iyanju pe, ko pọn dandan ki gbogbo wọn dije dupo ninu idibo abẹle.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Wọn wa rọ wọn lati mu oludije kan gboogi ti yoo le soju won ninu idibo si ipo gomina naa.

Sẹnetọ to n soju ẹkun idibo iwọ oorun ipinlẹ Kogi nile Asofin Agba, Sẹnetọ Dino Melaye wa lara awọn to n dije dupo gẹgẹ bii ẹni ti yoo gbe asia ẹgbẹ oselu PDP ni idibo sipo gomina to n bọ.

Lara awọn to fi ipo silẹ fun Wada ni:

  • AVM Salihu Atawodi,
  • Muhammed Tetes,
  • Emmanuel Omebije,
  • Mrs Grace Iye Adejor,
  • Dr. Victor Adoji.

Nibayii, gbogbo eto lo di doju ọgbagade ninu ẹgbẹ oselu PDP bayii fun eto idibo abẹnu naa to n waye loni ọjọ Isẹgun.

Oludije to ba si moke ninu awọn oludije PDP yii ni yoo koju gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello lati ẹgbẹ oselu APC, ninu idibo gomina ti yoo waye ni Ọjọ Kẹrindinlogun, Osu Kọkanla, ọdun 2019.