WAEC: Ìdá 82% àwọn tó jókòó ṣedánwò WASSCE 2019 ló yege

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ onidanwo mẹwaa, WAEC ti gbe esi idanwo aṣekagba ileewe girama ti oṣu kẹfa, ọdun yii, West African Senior School Certificate Examination (WASSCE) jade.
Ajọ naa sọ eyi di mimọ nilu Eko.
- Israel Adebajo: Ìlúmọ̀ọ́ká oníṣòwò tó fi òkò Stationery Stores pa ẹyẹ púpọ̀
- Bíbéèrè fún ìbálòpọ̀ gbogbo ìgbà sọ ìyàwó ilé dèrò ilé ìwòsàn
- Ìjọba ti bẹ̀rẹ̀ sí báwọn tó gbé òṣìṣẹ́ aláàánú mẹ́fà sọ̀rọ̀- Garba Shehu
- Waec f'ofin de ile'we mẹtadinlaadọta
- Àwọn akẹ́ẹ̀kọ́bìnrin fakọyọ ju akẹ́kọkùnrin ní'dánwò WAEC
Ajọ naa ti wa rọ awọn akẹkọọ to joko ṣe idanwo naa lati bẹrẹ si nii lọ wo ori ayelujara fun esi wọn.
Nnkan bii miliọnu kan abọ o le diẹ lawọn akẹkọọ to joko ṣe idanwo naa lọdun yii eyi to pọ ju ti esi lọ.
Gẹgẹ bi ajọ WAEC ṣe sọ ọ, ida mejilelọgọrin ni awọn akẹkọọ to gba ami o kare, iyẹn credit ni awọn iṣẹ ọpọlọ marun un tabi ju bẹẹ lọ.
Eyi fẹrẹ to ilọpo meji awọn to ni iye ami yii ninu idanwo ọdun 2018, eleyi to jẹ ida aadọta o din diẹ, 49.98%.










