Ondo State: Àwọn aláṣẹ Poly Rufus Giwa di ítì pa di ọjọ́ iwájú

Oríṣun àwòrán, Google
O ṣeese ki igbesẹ awọn alaṣẹ ile iwe giga gbogboniṣe Rufus Giwa to wa ni ilu Owo, ipinlẹ Ondo pa awọn akẹkọọ lara.
Iṣẹju diẹ sẹyin ni ikede naa jade pe lati oni ọjọ iṣẹgun ikejidinlogun oṣu ikẹfa pe ile iwe giga gbogboniṣe Rufus Giwa Polytechnic di titi pa.
Eyi waye lẹyin atẹjade ti igbimọ alaṣẹ ile iwe naa fi sita pe awọn fi ikede ranṣẹ si gbogbo ọmọ ile iwe lati kuro ninu ile iwe ko to di agogo mẹta ọsan oni.

Oríṣun àwòrán, Rufus Giwa Polytechnic
Iwe naa ti Sule Atiku to jẹ adele Giwa ile iwe naa fọwọ si ṣalaye pe igbesẹ naa ṣe pataki lati yanju ọrọ to ni ṣe pẹlu riru ofin.
Ẹ̀wẹ̀, nigba ti BBC Yoruba kan si alaga ẹgbẹ awọn olukọni ile iwe giga naa ASUP, Ọgbẹni Ijawo Rafiu jẹ ko di mimọ pe oun woye pe tori iwọde alafia ti awọn gun le lo fa a.
Ẹgbẹ ASUP ni iwọde awọn wa lati fi ẹhonu han lori ainaani itọju oṣiṣẹ ti awọn alaṣẹ gbe wọ bi ẹwu. Ko da tori eyi wọn ni awọn atawn alaṣẹ jọ pa ẹnu pọ pe ki wọn sun idanwo awọn akẹkọọ to yẹ ko bẹrẹ ni ọjọ kẹtadinlogun oṣu ikẹfa siwaju.
Iwọde ẹgbẹ ASUP tun da lori owo oṣu ti wọn n jẹ wọ fun odidi oṣu mẹfa, ai ṣe igbega lẹnu iṣẹ lati ọdun 2017 wọn si tun din yọ ninu owo oṣu wọn.

Oríṣun àwòrán, Rufus Giwa Polytechnic
Bakan naa ni ẹgbẹ ASUP fi iwe sita to ṣalaye bi awọn ati awọn alaṣẹ ile iwe naa ṣe jọ tọwọ bọ'we adehun lori awọn koko ti wọn bere fun ati esi awọn alaṣẹ naa.
Iwe adehun yii yanana ọrọ igbega lẹnu iṣẹ, owo oṣu ati dida owo oṣu ti wọn yọ pada.
Igbiyanju lati kan si Giwa ile iwe naa ko tii yọri si rere bo tilẹ jẹ wi pe awọn aṣoju alaṣẹ naa buwọlu iwe adehun naa nibi ipade to waye laarin wọn ati ẹgbẹ ASUP.














