Chinese restaurant: CDHR ní ìjọba Nàíjíríà ló fa ẹ̀gbin náà bá wa

Oríṣun àwòrán, Punch
Aarẹ ajọ ajafẹ́tọ ọmọ Naijiria ti a mọ sí CDHR, Amofin Malachy Ugwummadu ti sọ wipe, ajọ naa ṣetan lati ja fun ẹtọ ọmọ Naijiria kan, ti ile iṣẹ ounjẹ awọn ọmọ ilẹ China to wa lorilẹede Naijria ko ba gba laaye, lati wọle jẹun nibẹ.
Igbesẹ yii waye lẹyin ti iroyin gba ori ayelujara kan wipe, ile ounjẹ China kan to wa ni Ikeja nilu Eko, Shi Shi Chinese Restaurant kọ, lati jẹ ki awọn ọmọ Naijiria wa ra ounjẹ ninu ileeṣẹ wọn.
Awọn akọroyin to lọ ṣe iwadii ni ile ounjẹ naa gbọ wipe, ootọ ni ati wipe, ileeṣẹ naa ni ọmọ Naijiria to ba fẹ ra ounjẹ ninu lọdọ wọn gbọdọ mu ọmọ orilẹede China kan lẹyin.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Afurasi kan fipá bá akẹ́kọ̀ọ́ UNILAG lò pọ̀, ó tún jí pátá rẹ̀ - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
- Ekiti: Ìjọba gbé ìgbésẹ túntún láti fí ìyà jẹ ẹni tó bá bá ọmọdé lòpọ̀
- Ìjì líle mú ẹ̀mí èèyàn 1000 lọ, odidi ìlú kan bàjẹ́
- A gba ìwé ìpẹ̀jọ́ ₦200m lọdọ mọlẹbi Sugar - UCH
- Owó dé! Ilé Aṣòfin Àgbà fòǹtẹ̀ lu N30,000 owó oṣù òṣìṣẹ́
Ṣugbọn Ugwummadu ni igbesẹ ileeṣẹ to ba dan iru nkan bayii wo lodi si ofin agbaye ati ti Naijiria.
Ninu ọrọ rẹ pẹlu BBC Yoruba, amofin naa ni oun ti ajọ CDHR nilo lati ọdọ ẹni ti ileeṣẹ okeere naa da pada lẹnu ọna, ni ẹri bii fidio tabi aworan ti yoo fi ohun to ṣẹlẹ han.

Oríṣun àwòrán, Bc
O ni ijọba orilẹede Naijiria lo fa iru ẹgbin bayii ba awọn ọmọ orilẹede yii, nitori awọn lo gbe aye le awọn ileeṣẹ okeere lọwọ.
Ijọba Ipinlẹ Eko ti fesi si ọrọ ile ounjẹ China naa pe, ko si ootọ kankan ni ọrọ naa, nitori wipe awọn ti ran awọn eeyan kan lọ si ileeṣẹ ounjẹ naa ni bonkẹlẹ, ti wọn si da wọn lohun.
Komiṣọna fun eto igbafẹ ní Ipinlẹ Eko, Steve Ayorinde, ti ni ijọba kò tíì pari iwadii rẹ lori ile ounjẹ China kan ni ipinlẹ Eko to n gbe igbesẹ ẹlẹyàmẹya ti ko jẹ ki awọn ọmọ Naijiria ra ounjẹ.
Ẹ gbọ ọrọ rẹ siwaju si:














