Wakanda Forever : Aubameyang fi 'Black Panther' dáwọ̀ọ́ ìdùnnú lórí pápá

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal bori ifidirẹmi goolu mẹta lọwọ Rennes ti wọn si pegede lati kopa ninu abala komẹsẹoyo idije Europa League.

Ṣugbọn kii ṣe goolu mẹta ti wọn jẹ tabi aṣeyọri wọn lawọn eeyan n sọrọ nipa rẹ bi ki ṣe awọ oju ti Aubameyang wọ lati fi dawọọ idunnu.

Kete ti o jẹ goolu rẹ keji lo sare lọ mu awọ oju iru eleyi ti wọn wọ ninu fiimu ''Black Panther'' ti o si dawọọ idunnu ''Wakanda Forever''

Ko ye wa si ẹni to fi awọ naa si ibi to ti mu ṣugbọn idawọọ idunnu yi lo gba ẹnu awọn eeyan loju opo Twitter.

Koda ẹgbẹ agbabọọlu rẹ Arsenal kan sara si fun ohun to ṣe yi

Ki lo muAubameyang dawọ idunnu Black Panther

Pierre Emerick Aubameyang to jẹ ọmọ orileede Gabon ko ṣẹsẹ ma wọ awọ oju lati fi dawọ idunnu lori papa.

Nigba ti o wa ni ẹgbẹ agbabọọlu Borussia Dortmund, a ma saba fi awọ oju Batman ati eyi keyi miran to ba wa si lọkan dawọ idunnu lẹyin to jẹ goolu.

Nipa ti Black Panther to wọ yi,ẹgbẹ agbabọọlu rẹ salaye lọju opo wọn pe o ni ohun wọ awo naa lati fi sapejuwe orukọ ikọ agbagbọọlu orileede wọn ti orukọ rẹ n jẹ ''Black Panthers''

Aseyọri ẹgbẹ Arsenal ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn yi tunmọ si wi pe awọn ati ẹgbẹ Chelsea yoo jijọ siwaju lati kopa ninu abala komẹsẹoyọ idije Europa League.