Ayò mẹ́ta ni Giroud fi fakọyọ fún ikọ̀ Chelsea nínú Europa League

Ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ti pegede lati kopa ninu abala komẹsẹoyọ Idije Europa League lẹyin ti wọn da bantẹ iya ayo mẹrin sodo fun Dynamo Kiev.

Ninu ifẹsẹwọnṣe naa to waye ni papa iṣere NSC Olimpiyskiy Stadium nilu Kiev,Ukraine,Olivier Giroud lagbabọọlu ẹgbẹ naa to fakọyọ.

Ami ayo mẹta lo jẹ ninu marun un ti Chelsea gba wọ ile Dynamo.

Ninu ifẹsẹwọnṣẹ akọkọ ti wọn gba ni Stamford Bridge,ami ayo mẹta si odo ni wọn fi sagba Dynamo.

Pẹlu esi yi,o jẹ ayo meje ti wọn gba wọle Dynamo ti eyi si j ki wọn tẹsiwaju lọ si abala ti o kan ninu idije ti ọdun yi.

Yatọ si Olivier Giroud,Alonso ati Callum Hudson-Odoi wa lara awọn ti wọn jẹ goolu ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.

Ni ọjọ ẹti ni wọn yoo ṣe aṣayan awọn ẹgbẹ agbabọọlu to pegede wọ abal;a komẹsẹoyọ ati awọn ti wọn yoo ba ṣalabapade