Vice Presidential Debate: Àwọn olùdíje n fọ̀rọ̀jomitoro

Aworan awọn oludije
Àkọlé àwòrán, Awọn igbakeji Aarẹ to n dije ni yoo kopa ninu ijiroro naa

Ifọrọjomitoro ọrọ laarin awọn igbakeji oludije ipo Aarẹ ninu idibo ọdun 2019 lorileede Naijiria ti n waye nilu Abuja

Ijiroro naa ti wọn pe ni 'The Peoples Debate' yoo fun awọn oludije laanfaani lati sọ erongba wọn fun ara ilu.

Ninu awọn oludije mẹfa ti wọn fi iwe pe,mẹta lo yọju iyẹn Rabiu Ahmed Rufai AAN,Kunle Olagbegi ti National Democratic Party ati Khadijah Abdullahi ti ẹgbẹ Alliance for New Nigeria ANN.

Gbọngan Ladi Kwali nilu Abuja ni o ti n waye.

line

Koko nnkan ti awọn oludije n sọ

Nipa Owo oṣu to kere fun osiṣẹ

Aworan awọn oludije
Àkọlé àwòrán, Kunle Olagbegi ati Ahmad Rufai

100,000 ni ẹgbẹ ADC ati ẹgbẹ AAC lawọn yoo san fun ara ilu gẹgẹ bi owo osu to kere julọ fun oṣiṣẹ

Kunle Olatẹru Olagbegi ti o jẹ igbakeji oludije Aarẹ ẹgbẹ ADC ati Rabiu Ahmed Rufai ti ẹgbẹ African Action Congress (AAC) nieyi nikan ni na ti awọn eeyan Naijiria yoofi jaanfaani ijọba.

Ahmed Rufai lawọn yoo gba 200,000 olukọni jakejado orileede Naijiria ati wi pe awọn yoo faye gba iṣẹ ohun amuludun lorisirisi.

ijiroro
Àkọlé àwòrán, Khadijat sọ pe fifikun owo osu oṣiṣẹ to kere ju lọ ki ṣe ọna abayọ fun eto ọrọ aje

Khadijat ni fifikun owo oṣu kọ ni ọna abayọ lati mu idagbasoke ba eto ọrọ aje.

O ni mimu idagbasoke ba ẹsẹpupu ni ibi ti o yẹ ki ijọba gbajumọ nipa ṣiṣe amulo awọn ohun alumọni ti Naijiria ni lọpọyanturu

Ọrọ Abo

Ahmed Rufai ni idahun si ibere ọrọ abo ni ko si iṣedeede ati idajọ ododo lorileede Naijiria.

O ni lilo ọtẹlẹmuyẹ to peye jẹ ọna lati koju ipenija Boko Haram.

O pe fun ajoṣepọ laarin awọn ajọ alaabo lorileede Naijiria.

Olori ti ko muna doko lo wa nidi gbogbo ipenija aabo.

Kola Olagbegi ni tirẹ di ẹbi ipenija aabo ru awn alaṣẹ ti ko munadoko.

Aworan awọn oludije
Àkọlé àwòrán, Kola Olateru Olagbegi

O pe fun ki wọn yọ awọn olori ileesẹ ọmọ ogun Naijiria ti wọn ti pẹ lori oye.

O nilabẹ ijọba awọn,awọn yoo pawọpọ plu ilẹ Gẹẹsi ati Amerika lati koju ipenija aabo to n ba Nijiria finra

Khadijah Abdullahi

Aabo to peye jẹ ọna kan gbogi ti Khadijah Abdullahi da laba lati koju ipenija aabo.

O ni ẹgbẹ awọn yoo ri pe awọn ọmọ ogun gba owo to yẹ ki wọn ba le ṣe iṣẹ wọn bo ti ṣe tọ ati bo ti ṣe yẹ

Ajọ ti ko niiṣẹ pẹlu ijọba kan ti orukọ wọn n jẹ 'Enough is Enough' lo sagbatẹru ijiroro naa pẹlu ajọsepọ ile isẹ BBC,TVC NEWS,BudgiT,One ati Transition Monitoring Group.

aworan gbagede ijiroro
Àkọlé àwòrán, BBC

Ninu awọn ti o n kopa ninu itako ọrọ naa lati ri oludije igbakeji Aarẹ awọn ẹgbẹ oṣelu bi PDP,Peter Obi, Yemi Osinbajo ti ẹgbẹ APC ,Shehu Gabam SDP ati Rabiu Ahmed Rufai AAC.

Umma Getso ti Young Progressive Party ati Khadijah Abdulahi Alliance for New Nigeria.

Ẹwo diẹ ninu awọn awọran lati gbagede ijiroro naa

Aliyu Tanko ti ileeṣẹ BBC àti Ngozi Aliegbu
Àkọlé àwòrán, Aliyu Tanko ti ileeṣẹ BBC àti Ngozi Alaegbu
ijiroro
Àkọlé àwòrán, Ijiroro