New Minimum Wage: Ilé ìgbìmọ̀ aṣojú ṣòfin bọwọ́ lu #30,000 fáwọn òṣìsẹ́

Oríṣun àwòrán, Twitter/NLC
Ile igbimọ aṣoju ṣofin l'Abuja ti buwọ lu aba lati maa san ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira gẹgẹ bi owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ.
Igbesẹ naa waye lẹyin ti igbimọ to n ri si alekun owo oṣu oṣiṣẹ tuntun jabọ fun ile.
Gbogbo ile lo fọwọ si pe ki ijọba bẹrẹ si san ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira gẹgẹ bi owo oṣu tuntun fun oṣiṣẹ to kere julọ fawọn oṣiṣẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Tani Kingsley Moghalu tó ń dupò ààrẹ Naijiria? #BBCNigeria2019
- À ṣì ń lọ sílé ẹjọ kòtẹmilọrùn - Ayodele fayose
- ‘A ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé Kayọde Fayemi ni yóò jáwé olúborí ní Tribunal’
- Ile Asofin Eko ránṣẹ́ pe Ambọde láti wá sọ tẹnu rẹ̀ lórí ẹ̀ṣùn aṣemáṣe
- A kò ṣe àyọnusọ lóri ọ̀rọ̀ abẹ́lé Nàìjíríà - UK
- Àwọn àwòrán ẹ̀yìn ìtàgé níbi ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá l'Eko
Eleyi wa ni ibamu pẹlu aba ti igbimọ ti Aarẹ Muhammadu Buhari gbe kalẹ lati ṣiṣẹ lori alekun owo oṣu tuntun fawọn oṣiṣẹ da.
Aarẹ Buhari ti kọkọ fọwọ si ẹgbẹ mẹtadinlọgbọn naira tẹlẹ ṣugbọn awọn oṣiṣẹ kọ jalẹ pe ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira lawọn yoo gba gẹgẹ bi owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ.









