Ọ̀gá ọlọ̀pàá Idris ni kí ẹ mu ti nnkankan ba ṣẹlẹ́ si mi -Saraki

Oríṣun àwòrán, @bukolasaraki
Ààrẹ ilè aṣòfin àgbà Bukola Saraki ti figbe sita pé Oga ọlọpaa orileede Naijiria, Ibrahim Idris n lepa ọna lati gbẹmi oun.
Saraki fi ọrọ yi to awọn akọroyin leti nigba ti o n bawọn sọrọ nilu Ilorin.
Bakan naa ni o kọ ọ si oju opo Twitter rẹ́ pẹlu ikilọ pe ki awọn eeyan mọ wi pe bi nnkankan ba ṣe ohun tabi mọlẹbi ohun, ọga agba ọlọpaa Idris ni ki wọn mu.
Saraki salaye pe awọn igbesẹ ti ọga ọlọpaa n gbe paapa julọ pẹlu awọn ọga ọlọpaa ipinlẹ́ Kwara to n parọ bi ẹni parọ aṣọ mu ifura lọwọ.
O ni lasiko yii ti ipolongo ibo yoo bẹrẹ ni pẹrẹwu, ọkan oun ko balẹ pe ọga ọlọpaa Idris ko ni gbe igbesẹ lati mu ahẹ ba abo oun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1

End of X post, 2
Lọjọ ẹti ni Saraki ni awọn janduku ọmọ ẹgbẹ APC kan yabo agbo ile oun ladugbo Agbaji nilu Ilorin .
Awọn ọlọpaa to wa nibi iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi Saraki se sọ ko gbe igbesẹ kankan lati di awọn janduku naa lọwọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Ile iṣẹ ọlọpaa ti fesi si ọrọ Saraki pe awọn ko fi igba kan fi ọwọ yẹpẹrẹ mu aabo oun ati mọlẹbi rẹ.
Ninu atẹjade kan lati ọdọ alukoro ile iṣẹ ọlọpaa, Jimoh Moshood, wọn ni ''ko si ootọ ninu ọrọ ti Saraki sọ ati pe awọn rọ ara ilu lati ma ṣe da a lohun''
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
Moshood ni awọn ko kin awọn janduku lẹyin lati ba nnkan jẹ lagbole Saraki ati wi pe awọn ko ri ẹsun kankan gba lawọn agọ ọlọpaa to wa nilu Ilorin ni ọjọ kẹwa titi di ọjọ kọkanla nipa idunkoko mọ ọ tabi awọn mọlẹbi rẹ.
Aawọ laarin Oga ọlọpa ati Saraki ko ṣẹṣẹ bẹrẹ
Bi a ko ba gbagbe fa ki n fa paapa julọ lori aṣẹ ti ile asofin pa ki Ọga ọlọpaa wa yọju sile asofin lori awọn ipaniyan kan to n waye lo dabi ẹni wi pe o da wahala silẹ.
Ọga ọlọpa Idris kọ lati yọju sile ti Aarẹ ile Bukọla Saraki si ni iwa rẹ ko jọ oun loju nitori pe a maa kọ iṣẹ fun ọga rẹ ti ṣe Aarẹ Buhari.
Iṣẹlẹ idigunjale to tun waye nipinlẹ Kwara naa wa lara ohun ti o mu ki awọn mejeeji ma gba ti ara wọn.
Ninu nnkan ti Saraki sọ loju opo Twitter rẹ, o ni gbogbo ọgbọn ni ọga ọlọpaa Idris n da lati ko panpẹ si oun lọwọ
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 5

End of X post, 6