NUJ: Kò yẹ kí akọ̀ròyìn fi ìròyìn tú àsírí ológun fún Boko Haram

Àkọlé fọ́nrán ohùn, NUJ: Ẹ̀yin Akọ̀ròyìn, ẹ sọ́ra nípa kíkọ ìròyìn tó léwu fétò ààbò

Ẹgbẹ awọn akọroyin lorilẹede Naijiria, ti kesi awọn awọn ọmọ ẹgbẹ naa lati mu eto aabo ilu lọkunkundun nipa didẹkun kikọ iroyin ti o le jẹ ki eto aabo mẹhẹ lorilẹede Naijiria.

Alaga ẹgbẹ akọroyin ni ipinlẹ Ọyo, Kọmureedi Adewunmi Faniran lo sọ eyi fun BBC Yoruba, lasiko to n fesi si bi ile iṣẹ ologun Naijiria, ṣe yabo ile iṣẹ iroyin Daily Trust ni Maiduguri ati Abuja.

Adewunmi ni, awọn akọroyin gbọdọ rọra lori eto aabo ilu, ki wọn si ṣọra lati ma a kọ awọn iroyin ti yoo fi han awọn ikọ Boko Haram wi pe, awọn ọmọogun n bọ wa ṣigun bo wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Alao Akala:Èmi àti Ajimọbi kò ṣe ìlérí kankan fún ara wa

O fikun wi pe, idunnu lo jẹ fun awọn wi pe awọn ologun ko lu ẹnikẹni, bẹẹ si ni wọn ko pa ẹnikẹni lasiko ti wọn yabo ileeṣẹ naa.

O wa parọwa si awọn ọmọogun ati awọn akọroyin lati ri wi pe, wọn n ṣe ijiroro lati igba de igba ki agbọye le wa laarin awọn agbofinro ati akọ̀ròyìn nigba gbogbo.

Àkọlé fídíò, Kwara yóò gbàlejò BBC Yoruba

Ti a ko ba gbagbe, Ọjọ Isinmi ni iroyin gbe jade wi pe, awọn ọmọogun Naijiria ṣigun bo ile iṣẹ Daily Trust.

Awọn ọmọ ologun kede pe, awọn gbe igbesẹ naa, nitori bi ilesẹ iroyin naa se fi aṣiri igbogun ti Boko Haram awọn lede ninu iroyin ti wọn gbe sita ninu iwe iroyin Daily Trust ni Ọjọ Karun, Osu Kini, ọdun 2019.