NANS: Àwọn aráàlú ní se ló yẹ kí NANS bẹ̀bẹ̀ fún òpin ìyansẹ́lódì ASUU

Aarẹ Buhari atawọn asaaju ẹgbẹ akẹkọ

Oríṣun àwòrán, @AsoRock

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti n sọrọ lori fidio kan to n ja rainrain nilẹ pe aarẹ ẹgbẹ awọn akẹ́kọ ile ẹkọ giga nilẹ wa, NANS, Danielson Bamidele Akpan, sọ fun aarẹ Muhammadu Buhari pe, yoo ri ibo ogun miliọnu laarin awn akẹkọ ilẹ yii.

Ọrọ yii ni wọn lo jẹyọ lasiko ti ẹgbẹ NANS lọ se abẹwo si aarẹ Buhari nile ijọba Aso Rock nilu Abuja.

Ninu fọnran aworan to lu sita lẹyin abẹwo naa, ni Akpan ti salaye pe awọn akẹkọ Naijiria pọ pupọ, ti wọn si fẹẹ to ọgọrin miliọnu niye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Akpan wa rọ aarẹ Muhammadu Buhari pe to ba lee lo ẹka yii bo se yẹ, oun n fi da loju pe, yoo ri ibo ti yoo to ogun miliọnu laarin awọn ọdọ naa.

Bakan naa ni awọn asaaju ẹgbẹ akẹkọ lo anfaani abẹwo wọn ọhun si ọdọ Buhari, lati ki ku ayẹyẹ oriire ọjọ ibi ọdun mẹrindinlọgọrin to pe loke eepẹ.

Àkọlé fídíò, Rashidat Fawẹhinmi: Sísọ èdè Yorùbá kò leè ba Gẹ̀ẹ́sì jẹ́ lẹ́yìn odi

Akpan tun gbadura fun Buhari pe, aseye ni yoo se ninu eto idibo aarẹ ti yoo waye losu keji ọdun yii.

Sugbọn ẹyin lohun, to ba ti jabọ, ko tun se ko mọ, awọn ọmọ orilẹede yii ti n sọ ero ọkan wọn lori ọrọ ti ohun ti aarẹ ẹgbẹ akẹkọ ilẹ wa naa sọ.

Lero tawọn eeyan kan, ohun ti Akpan ba lọ si Aso Rock kọ lo kọju mọ, kaka ko si maa bẹ Buhari pe ko dahun awọn ibeere tawọn olukọ fasiti n beere lọwọ ijọba, ọrọ oselu lo mojuto.

Aarẹ Buhari atawọn asaaju ẹgbẹ akẹkọ

Oríṣun àwòrán, @AsoRock

Lawọn oju opo ikansiraẹni, paapa Twitter, awọn ọmọ Naijiria kan ni, bi ẹgbẹ awọn olukọ fasiti se n wo isẹ niran lo yẹ ko mumu julọ laya awọn akẹkọ yii, ki wọn si wa ọna ti ijọba ati ASUU yoo se fi eegun otolo to aawọ aarin wọ.

Koda, awọn miran tiẹ foju laifi wo kaadi ọjọ ibi ti ẹgbẹ akẹkọ naa gbe fun Buhari lati fi ki ku oriire ọjọ ibi.

Aarẹ Buhari atawọn asaaju ẹgbẹ akẹkọ

Oríṣun àwòrán, @AsoRock

Jikan Sabo, @Usmern_ssg, o ni se ẹgbẹ NANs to n dun mahuru-mahuru laipẹ yii lati tẹsẹ bọ sokoto kanna pẹ́lu Buhari, lo wa n pada fun ni kaadi ọjọ ibi yii?

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Ogeadiro_official, @ogeadiro1 naa kin Jikan lẹyin pẹlu afikun pe Naijiria yoo maa bajẹ si ni.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Coker Pẹlumi, @ cokeroluwapelu2 woye pe ileri ibo ti aar ẹgbẹ NANS se fun Buhari yii, lo se afihan bi ẹka asaaju ẹgbẹ NANs ti bajẹ, to si jẹra si.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

@mrtsmilez lero tiẹ ni orilẹede Naijiria ree, nibi ti gbogbo wa ti jẹ ọdaran, ti aarẹ ẹgbẹ akẹkọ si ti gba owo.

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Ogunranti Abiodun, @Wonder_11 sọ loju opo Twitter rẹ pe, ọkan aarẹ ẹgbẹ NANs ti daru, to si n mu idarudapọ wa gẹgẹ bi orukọ rẹ ti fihan, o ni ko yara tete yọ orukọ toun kuro ninu ogun miliọnu akẹkọ ti yoo dibo fun Buhari.

Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 5