APC Kwara: Igun Bolarinwa ní àwọn ni alága ẹgbẹ́ tọ́ sí

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ APC ń se ipolongo ita gbangba

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ilé ẹjọ́ gíga ti Ilorin ní Ọjọ́ọ̀rú ọ̀sẹ̀ yìí dá ẹjọ́ pé Ishola Balogun -Fulani ni Alaga ẹgbẹ òsèlú APC ní ìpínlẹ̀ Kwara.

Igun Bashir Bolarinwa ti ẹgbẹ oselu APC ni ipinlẹ Kwara ti gba ile ẹjọ kotẹmilọrun lọ, lẹyin ti ile ẹjọ giga ni ipinlẹ Ilorin sọ wi pe awọn kọ ni wọn yọ ni alaga ẹgbẹ.

Ọjọbọ ọsẹ yii ni ile ẹjọ giga ni ipinlẹ naa sọ pe Ishola Balogun Fulani ati ikọ rẹ ni alaga ẹgbẹ naa ni ipinlẹ Kwara.

Igun Bashir wa n rọ ile ẹjọ kotẹmilọrun lati da ẹjọ naa nu, ki wọn si da awọn pada si ipo gẹgẹbi alaga ẹgbẹ to yanju.

Ti a ko ba gbagbe, alaga gbogboogbo fun ẹgbẹ oselu APC, Adams Oshiomole naa sọ ni Ọgbọnjọ, Osu Keje, ọdun 2018 wi pe oun ti tu igbimọ ẹgbẹ ka ni ipinlẹ Kwara, lẹyin ti aarẹ Ile Igbimọ Asofin Agba, Bukola Saraki fi ẹgbẹ silẹ lọ si ẹgbẹ oselu PDP.