Ogoni: Ṣé nǹkan ti yàtọ̀ lẹ́yìn tí Ken Saro-Wiwa fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀?

Ken Saro wiwa

Oríṣun àwòrán, TIM LAMBON / GREENPEACE

Àkọlé àwòrán, Awọn ogoni ko le gbagbe Ken Saro Wiwa, akoni tootọ

Ni ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹwaa, lọdun 1995 ni ile ẹjọ ologun kan dajọ iku fun Ken Saro Wiwa atawọn akẹgbẹ rẹ mẹjọ ti wọn n ja fun irapada ayika agbegbe Ogoni lorilẹ-ede Naijiria.

Ẹsun ipaniyan ni wọn fi kan wọn, ijọba ologun nigba naa labẹ ọgagun Sani Abacha fi ẹsun kan wọn pe wọn lọwọ ninu iku awọn agba ilẹ Ogoni mẹrin kan.

Ọjọ kẹwaa, oṣu kọkanla, ọdun 1995 ni wọn pa wọn.

Ni igba aye rẹ, Ken Saro Wiwa ko jẹ ki awọn ileeṣẹ ìwapo rọ̀bì lẹkun naa o sinmi nitori awọn idibajẹ ti aibikita iṣẹ wọn n ko ba ayika nigba naa.

Titu epo si oju agbami, eleyi to n ṣe ọpọ akoba fun awọn ohun abẹmi ninu omi agbegbe naa. n mu inira nla ba awọn eeyan ibẹ nitori iṣẹ ẹja pipa ni gbajugbaja iṣẹ nibẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Tony Elemelu Foundation: Gbogbo okòwò ló ní ìdojúkọ

O si da ẹgbẹ ajijagbara MOSOP lati ja fun ẹtọ ayika agbegbe Ogoni.

Bakan naa ni eyi n fa arun fun awọn eeyan agbegbe Ogoni ti wọn n mu omi bẹẹ tabi lò fún ọ̀gbìn wọn.

Ileeṣẹ ìpọnpo Shell ni Ken atawọn ajafẹtọ ilẹ Ogoni yooku na ika aleebu si julọ nigba naa.

Ni ọdun 1941 ni wọn bi Ken Saro-Wiwa, itara idagbasoke fun agbegbe Ogoni ti o mu'mu ni aya rẹ lo si faa ti wọn fi lee kuro lẹnu iṣẹ ni ipinlẹ Rivers lọdun 1973.

Awọn oluwọde kan nwọde

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Saro-Wiwa da ẹgbẹ ajijagbara MOSOP lati ja fun ẹtọ ayika agbegbe Ogoni.

Lai naani oniruuru ipe ati ẹbẹ ti o waye latọdọ awọn ọmọ ilẹ Naijiria ati ni oke okun, ijọba ologun Sani Abacha pa Saro Wiwa.

Koda, alaga igbimọ awọn Oludari agba ni ileeṣẹ ipọnpo rọbi Shell nigba naa, Cor Herkstroter pẹlu fi lẹta ẹbẹ ranṣẹ si Ọgagun Sani Abacha nigba naa pẹlu.

Ninu ọrọ kan to ba ileeṣẹ iroyin BBC kan sọ ni BBC's Newsday ni ọdun 2015, Suzanne Dhaliwato, to jẹ ọmọ ẹgbẹ ajafẹtọ kan ti a mọ si, Action Saro-Wiwa ni, "Iwa kan naa ti ijọba hu si ẹtọ ati wi tẹnu ẹni ni ogun ọdun sẹyin ni a ṣi n ri bayii."

Arabinrin kan n pọn omi ninu odo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ileeṣẹ ipọnpo Shell ni Ken atawọn ajafẹtọ ilẹ Ogoni yooku na ika alebu idibajẹ ayika agbegbe Ogoni si julọ

Lẹyin iku rẹ iyatọ diẹ lo tii de ba agbegbe Ogoni lori atunṣe ati irapada ayika ibẹ. Eyi lo fa oniruuru ijijagbara to dide lẹyin rẹ bi MEND ati awọn ọdọ agbebọn ti wọn dide ki o to di pe ijọba apapọ laye aarẹ Musa Yaradua ṣeto idariji eleyi ti o mu alaafia pada si agbegbe aaringbungbun guusu orilẹ-ede Naijiria, (South-south)

Abajade iwadii kan ti ajọ iṣọkan agbaye gbe jade ni ọdun 2011 ṣalaye pe yoo fẹrẹ to ọgbọn ọdun ki agbegbe Ogoni to lee bọ lọwọ ọṣẹ ti epo rọbi ti wọn tu si ayika rẹ ṣe nibẹ.

Ajọ UN ni "eyi yoo nilo eto afọmọ to jinlẹ nibẹ"

Ibudo ipọnpo nla

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ni ọdun 1941 ni wọn bi Ken Saro-Wiwa, itara idagbasoke fun agbegbe Ogoni lo faa ti wọn fi lee kuro lẹnu iṣẹ ni ipinlẹ Rivers lọdun 1973

Aarẹ Muhammadu Buhari ni ibẹrẹ saa iṣejọba rẹ ṣeleri eto atunṣe agbegbe naa ti igbakeji rẹ, Yẹmi Oṣinbajọ si ṣe ifilọlẹ eto naa ni oṣu kẹfa, ọdun 2016 ṣugbọn titi di bi a ṣe n sọrọ yii, ko tii si ohun kan pato ti eniyan lee ri dimu lori eto naa nibẹ.

Kii ṣe ijijagbara nikan ni Ken Saro wiwa ṣe nigba aye rẹ. Onkọwe ti gbogbo agbaye mọ ni.

Ninu ọpọ iwe rẹ, a maa gbiyanju ati ṣe afihan ohun ti oju awọn eeyan rẹ n ri nitori agbegbe wọn ti awọn to n wa epo rọbi n fi igba gbogbo bajẹ.

Lara awọn iwe ti o kọ ni: Forest of Flowers (1986).

Àkọlé fídíò, Ìwà olè, jìbìtì àti ìjẹkújẹ ló n jé káwọn mii yí ọjọ́ orí wọn padà