Iléeṣẹ́ China kan ti fagídí mú àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ mu ìtọ̀

aayan

Oríṣun àwòrán, Science Photo Library

Àkọlé àwòrán, Aayan fẹ jó, adiyẹ ni kò jẹ́

Awọn oluṣakoso ilé-iṣẹ́ kan ni ìlú China ti fẹwọn gbára nitori wọn n fun oṣiṣẹ wọn ni itọ mu.

Bakan naa ni wọn fẹsun kan wọn pe wọn n fun wọn ni aáyán jẹ nítorí wọn kò bá afojusun ìdíyelé ọjà títà.

Awọn ọlọpaa ti gbé ìgbésẹ lẹyìn tí àwọn fidio tí o ṣafihàn bíi wọn ṣe n fí igbanu da seriya fun oṣiṣẹ náà tí o sí tún n mu omi tó jọ ito jade.

Ẹrọ ayélujára sí ti sọ pe wọn ni ki oṣiṣẹ wọn maa jẹ aayan tí wọn kò bá ba afojusun idiyele ọja wọn

Àkọlé fídíò, Ìnú mi kìí dùn nígbà trí mo ń ṣiṣẹ́ ni bánkì tó ìgbà ti mo bẹ̀rẹ̀ mẹkáníìkì

Oluṣakoso mẹta ní wọn sì ti rán lọ sí ẹwọn fún ọjọ máàrún ati mẹwaa lórí ìṣẹlẹ náà.

Fidio kan ti wọn pin káàkiri lori ẹrọ ayélujára Weibo ni ìlú China fihàn tí oṣiṣẹ kunrin kan ti duro láàrin ibìkan ti wọn ti n lu ni kumọ.

osise

Oríṣun àwòrán, Pearvideo.com

Àkọlé àwòrán, Gbogbo ẹ di mimọ lataari fidio to jade lori ayelujare

Awọn oṣiṣẹ kan ti wọn jọ pé ilé-iṣẹ́ àtúnṣe ilé ni ìlú Guizhou ni wọn n bá ṣiṣẹ ni ó jọ lori bí wọn ṣe n mu omi tó jọ itọ ninu kọọpu ati bi wọn ṣẹ n di imu wọn fun oorun.

Ìròyìn sọọ dì mimọ pé ilé-iṣẹ́ náà kọ̀ lati san owo osu oṣiṣẹ fún oṣù méjì, ẹrú sí n bá àwọn oṣiṣẹ náà láti sọrọ jáde nítorí wọn o fe pàdánù owo wọn ti wọn bá dawọ iṣẹ dúró.

itọ

Oríṣun àwòrán, Pearvideo.com

Àkọlé àwòrán, ìtọ̀ di ohun mimu ni China

Awọn ọlọpaa ìpín Zunyi mu awọn oluṣakoso mẹta, wọn sì tí gbà idajọ ẹwọn.