Boko Haram: Ẹgbẹ́ BBOG sèwọ́le l‘Abuja tako ìkú Hauwa Leman

Ẹgbẹlẹgbẹ awọn ọmọ ẹgbẹ ajafẹtọ, labẹ ẹgbẹ to n pe fun idapada awọn ọmọdebinrin wa ti Boko Haram ji gbe, Bring Back our Girls (BBOG), lo peju si gbagede Unity Fountain ni aarọ oni nilu Abuja, lati wa fi ẹhonu wọn han lori bi ikọ Boko Haram se gbẹmi osisẹ kan, to n sisẹ pẹlu ẹgbẹ alaanu Red Cross.
Arabinrin naa, Hauwa Leman ati awọn akẹgbẹ́ rẹ ni awọn alakatakiti ẹsin ọhun ji gbe, lẹyin ti wọn ṣe ikọlu si ibudo ológun kan to wa ni Rann, ni ipinlẹ Borno.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìdájọ́ ikú ń dínkù, àmọ́ orílẹ̀-èdè mélòó ló sì ń pa ẹlẹ́sẹ̀?
- 'Buhari wá sọ tẹnu ẹ'
- Ọgọ̀rọ̀ èèyàn s'ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọgọ́rin ọdún fún Fẹla
- Oluwo gba Aláàfin nímọ̀ràn pé kí olorì máa dé adé
- Kíni itumọ àṣẹ wàá tí àwọn Ààrẹ orílèèdè má n pá?
- Aláàfin ń se ọgọ́rin ọdún, àwọn àwòrán mánigbàgbé
- Kí ni àyájọ́ ‘Má wọ kọ́mú’ wà fún?
Gbogbo awọn ajafẹtọ ẹni to peju sibi iwọde naa ni oju wọn kọrẹ lọwọ, ti wọn si n kesi ijọba apapọ lati tete wọna ti yoo fi doola ẹmi awọn eeyan to wa ni igbekun Boko Haram, ki wọn to da ẹmi wọn legbodo.
Koda, adari ikọ BBOG, Oby Ezekwesili gan ko lee pa ọ̀rọ mọra, to si bu sẹkun gbaragada nibi iwọde naa.

Awọn ajafẹtọ ilu to ba BBC sọrọ ni, o se ni laanu pe Boko Haram si n pa awọn ọmọdebinrin wa lai naani oniruuru iwọde tawọn ti se tako iwa isekupani bayii.

Oríṣun àwòrán, Other
Wọn wa foju laifi wo iwa kawọn adunkoko mọni maa mu awọn eeyan lẹru nibi ti aye laju de yii, ti wn si n kesiawujọ agbaye lati sugba ijọba apapọ, ko lee rẹyin iwa aidaa naa, nitori ẹru ọran Boko Haram yii wuwo fun ijọba Naijiria nikan lati gbe.
Gbogbo akoko ti iwọde naa fi waye si lawọn agbofinro fi duro wawawa, aibaamọ, iwọde naa lee la jagidi-jagan lọ.
Boko Haram to pa osisẹ́ Red Cross nu awuye-wuye lọwọ
Loju opo ayelujara ati loju awọn iwe iroyin lorileede Naijiria, orukọ ọdọmọbirin kan, Hauwa Leman to n sisẹ pẹ́lu awọn ajọ alaanu Red Cross n ja rain-rain.
Ọrọ naa ko sẹyin pe ikọ alakatakiti agbesunmọmi Boko Haram dẹmi rẹ legbodo.
Toun ti ẹbẹ ti awọn ara ilu ati ijọba bẹ wọn, pe ki wọn ma se pa Hauwa Leman, sibẹ Boko Haram kọ jalẹ, wọn sẹmi rẹ lofo.
Ero araalu nipa iku Hauwa
Iwa laabi yi dori agba ati ọmọde kodo, ti awọn eeyan si n fi itara wọn han loju opo ayelujara.
Lero ọkan awọn ara ilu kan, ijọba lo kuna lati doola ẹmi Hauwa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1

End of X post, 2

End of X post, 3
Iha wo ni ijọba kọ si iku Hauwa latọwọ Boko Haram
Ijọba apapọ Naijiria ti saaju fi ibanujẹ ọkan rẹ̀ han lori bi ikọ̀ agbesunmọmi Boko Haram se pa Hauwa.
Ninu atẹjade kan ti Minisita fun eto iroyin ati ibanisọ́rọ Lai Muhammed fi sita,awọn sa gbogbo apa wn lati ri wi pe Hauwa pada wa sile layo ati alafia
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
Ọjọ Aje ni awọn ọmọ ikọ naa sẹkupa Hauwa Leman, lẹyin ọpọlọpọ ojọ ti wọn ti mu u si ahamọ wọn.
Hauwa jẹ́ ọ̀kan lara awọn oṣiṣẹ àjọ ICRC, to n pese iranlọwọ fun awọn to ti lugbadi ikọlu ikọ Boko Haram.
Hauwa ati awọn akẹgbẹ́ rẹ, Saifura to jẹ agbẹ̀bí, to fi mọ Alice, ti oun jẹ oṣiṣẹ nọọsi ni awọn alakatakiti ẹsin ọhun ji gbe, lẹyin ti wọn ṣe ikọlu si ibudo ológun kan to wa ni Rann, ni ipinlẹ Borno.
Ninu oṣu Kẹsan an ni wọn ṣekupa Saifura Ahmed ni tiẹ, ti wọn si dunkooko pe, awọn yoo tun pa ẹlomii ti ijọba ko ba fi ṣe ohun ti awọn n fẹ fun awọn.

Oríṣun àwòrán, @Twitter/ICRC
Ṣaaju ni ajọ alagbelebu pupa ti wọn n ṣiṣẹ fun, ICRC, rawọ ẹbẹ pe, ki wọn da ẹmi wọn si latari bi gbedeke ti ikọ Boko Haram fun ijba ṣe ku diẹ ko pari.
Ninu atẹjade kan to fi sita ni ilu London, Minisita fun eto iroyin ati aṣa, Lai Mohammed, ṣapejuwe iṣekupani ọhun gẹgẹ bi aibikita fun ẹmi ọmọnikeji, ati aini ibẹru Ọlọrun, nitori ko si ohunkohun to sọ gbigba ẹmi ẹlomii di ohun to tọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 5
Lai Muhammed to ba mọlẹbi oloogbe kẹ́dùn sọ pe, ''o ṣe ni laanu pe wọn paapa gba ẹmi ọdọmọbinrin naa lai fi ti gbogbo ariwo, ikede, ẹ̀bẹ̀, ati iduna-dura ti ijọba ṣe pe ki wọn tu u silẹ.''

Oríṣun àwòrán, AFP
Lai sọ pe ''lootọ ni iku ọmọbinrin naa dun ijọba, ṣugbọn wọn ko ni jẹ ki eyi mu irẹwẹsi ba wọn lati dẹ́kun iduna-dura fun idande awọn obinrin tó kù sí ahamọ.''
O wa a dupẹ lọwọ ''gbogbo awọn ọ̀rẹ́ orilẹ-ede Naijiria, to fi mọ awọn olórí ẹ̀sìn, to n ṣiṣẹ pẹlu orileẹde naa lati le ri itusilẹ gba fun gbogbo awọn obinrin ti Boko Haram fi si ahamọ rẹ.