Red Cross: Irọ́ ni pé á ń duna-dura pẹ̀lú Boko Haram

Oríṣun àwòrán, @nrc_ng
Agbarijọpọ ẹgbẹ alagbelebu pupa l'agbaye (Red Cross) ti kede pe, oun kii duna-dura pẹlu ikọ adunkooko mọni kankan lori awọn ti ikọ naa ji gbe.
Agbẹnusọ fun ẹgbẹ naa, Alexsandra Matijevic Mosimann, to fi ikede naa sita ni, ko sootọ kankan ninu awọn iroyin kan to n jade pe, oun ba ikọ Boko Haram sọrọ lati da awọn to mu si ahamọ silẹ.
O ni ṣiṣe bẹẹ yoo pagidina ohun ti ẹgbẹ Red Cross duro fun, eyi ti i ṣe aiṣègbè tabi fifi ara ti ẹnikẹni.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ọpọlọpọ eniyan ni ikọ agbesunmọmi Boko Haram ti ji gbe lapa Iwọ-Oorun Ariwa orilẹ-ede Naijiria, ti eyi si n mu ki orisirisi ajọ alaanu nilẹ okeere ati l'abẹle, to fi mọ awọn ẹlẹyinju aanu, maa pese iranlọwọ fun awọn ti ikọlu Boko Haram ti sọ di alainile lori.

Oríṣun àwòrán, AFP
ICRC ti wa ni ohun kan ti oun le ṣe gẹgẹ bi iranlọwọ ni lati pese eto irinna fun awọn ti wọn ji gbe pada si ile wọn.









